ADC ki i ṣẹgbẹ oṣelu kekere nipinlẹ Ogun, a ṣetan lati gbajọba lọdun to n bọ-Oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin Ifọ keji. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 21 September 2026

ADC ki i ṣẹgbẹ oṣelu kekere nipinlẹ Ogun, a ṣetan lati gbajọba lọdun to n bọ-Oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin Ifọ keji.


Onarebu Sadiq Azeez Babatunde, oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin fun Ifọ keji, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC,nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ẹgbẹ wọn ti kọja eyi ti wọn le ma foju tẹmbẹlu, nitori awọn ti ṣetan lati gba akoso nibi ibo to n bọ lọdun 2027.

Gẹgẹ bo ṣe wi, bi ẹru lawọn ṣe jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu yooku nitori wọn ko mọ ibi ti wọn yoo gba yọ si wọn lọdun to n bọ.

O ṣalaye siwaju pe imọlẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti tan kalẹ nibi gbogbo nipinlẹ Ogun titi to fi de awọn igberiko, eyi to mu kawọn araalu maa ṣatilẹyin fun wọn.

Oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin naa tun ṣalaye pe ẹ o rii pe lọdun to kọja nibi ibo to waye lọdun 2023, ipo kẹta lawọn ṣe, ṣugbọn lakooko yii nibi ibo to n bọ, awọn ni yoo gbegba oroke.

Lori erongba ẹ lati di ọmọ ile igbimọ aṣofin, Sadiq Babatunde sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun atilẹyin toun ri gba lati ọdọ awọn eeyan oun ni ẹkun Ifọ Keji.

O ṣalaye pe awọn eeyan ni wọn fẹ ki ayipada rere deba ijọba to wa lode yii, ti wọn si ti ṣetan lati fi kaadi idibo wọn le wọn jade.

Nitori ẹ ni wọn ṣe n fi ọkan oun balẹ pe awọn yoo rii pe wọn fi ibo wọn gbe e oun wọle.

O ṣalaye pe gbogbo nnkan to n jẹ afojusun oun lakooko yii ni bi irọrun, itẹsiwaju ati idagbasoke yoo ṣe deba awọn toun fẹẹ ṣoju fun, ti wọn ba dibo yan oun wọle.

O sọ pe awọn agbegbe kan wa ni Ifọ Keji, to jẹ pe inu inira ni wọn wa, idi ni pe gbogbo igba ni wọn maa sunkun sijọba lọrun lori ipo ti agbegbe wọn wa ṣugbọn ti wọn ko ri wọn ro, iru awọn bẹẹ ni mo maa kọkọ gbe igbesẹ le lori nile igbimọ aṣofin.

O tun ṣalaye siwaju pe eto ẹkọ, ilera fawọn araalu, imayedẹrun, ọrọ aje atawọn nnkan mii jẹ awọn opo pataki toun fẹẹ ṣiṣẹ le lori ati bi abo wọn yoo ṣe fẹsẹ rinlẹ.

O wa rọ awọn ara ipinlẹ Ogun lati dide atilẹyin fun ẹgbẹ ADC, ipinlẹ Ogun, fun ibo to n bọ, ki wọn si fi kaadi idibo wọn le APC wọgbo.

No comments:

Post a Comment

Pages