Ṣẹgun Ṣowunmi pariwo: Ẹ ma jẹ ki Atiku da wa pada sẹyin o, Ẹ jẹ ka fun Tinubu laaye lati depo aarẹ lẹẹkeji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 21 September 2026

Ṣẹgun Ṣowunmi pariwo: Ẹ ma jẹ ki Atiku da wa pada sẹyin o, Ẹ jẹ ka fun Tinubu laaye lati depo aarẹ lẹẹkeji


Agba oṣelu nni, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ti sọ pe bigba ti wọn ba fẹẹ da orileede wa pada sẹyin loun ri erongba Alaaji Atiku Abubakar, oludije aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC si lori bo ṣe sọ pe oun yoo da afikun lori owo epo pẹtiroolu pada boun ba wọle ibo to n bọ lọdun 2027.

Oludasilẹ ẹgbẹ toun wa ọna abayọ iyẹn The Alternative sọrọ ọhun lakooko to n ṣe ifilọlẹ kiko awọn eeyan jọ lati ṣatilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun saa keji ipo aarẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni bigba ti Atiku fẹẹ da wa pada si oko ẹru nilẹ Egypit loun ka si ati pe oun ko fọwọ si igbesẹ naa nitori akoba nla ni yoo jẹ fun ọrọ aje lorileede yii ti yoo si tun mu ifasẹyin wa.

Ṣowunmi tun ṣalaye siwaju pe a ti tiraka lori ọrọ afikun owo epo lorileede yii eyi to ni wọn bẹrẹ lọdun 1973. O ni latigba naa titi di akoko yii ko mu eso gidi kankan jade.

O ni ka lo mu ere gidi jade wa gbogbo wa ni yoo ti foju ri.

Ṣowumi sọ pe, "Mo fẹẹ ki a mọ pe ka ni afikun owo epo yii ṣe wa lanfaani gbogbo wa ni yoo ti foju ara wa rii, ọpọ ile ifọpo ni wọn pati fun aimọye ọdun ti wọn ko ṣatunṣe lee lori".

O waa lo akoko naa lati beere lọwọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria pe n jẹ o yẹ ki wọn tun da wa pada sẹyin, o ni iwaju la o maa lọ, a ko tun gbọdọ pada sẹyin mọ.

Ọtunba Ṣowunmi tun sọ pe lọpọ ọdun sẹyin loun ti ja fun ọrọ aje ati ipa ti iṣakoso ijọba Tinubu n ko lori ẹ pe o gbiyanju.

O ni ipawowọle lawọn ẹka mẹtẹẹta ijọba lo ti gberu si daadaa.O ni a ti wa ṣe debi pe bi owo ti wa nijọba ibilẹ, lo wa nipinlẹ bẹẹ lo tun wa nijọba apapọ pẹlu.

Bẹẹ lo tun wa bẹbẹ lati jẹ kijpba to wa lode yii tẹsiwaju nitori pe o ni yoo ran eto ọrọ aje wa lọwọ lọna to pọ.

O sọ pe ko yẹ ki a maa parọ ijọba laarin ọdun mẹrin nitori ijọba tiwa-n-tiwa ṣoro lati le ṣe awọn nnkan to yẹ lakooko.

Ṣowunmi fikun un pe, "Mo ti bẹrẹ igbesẹ lati igberiko fun kiko awọn eeyan jọ lati ṣatilẹyin fun ibo ọdun to n bọ. Mo ti ro wọn lagbara lati maa lọ kaakiri fun ipolongo".

O ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni aarin gbungbun Ogun lawọn yoo tan ipolongo yii de lati jẹ ki wọn mọ pe Tinubu gbọdọ wọle ẹlẹẹkeji.

Bẹẹ lo sọ pe oun ko bẹru awọn alatako oṣelu nilẹ Yoruba, o ni bi akoko ba to gbogbo wọn ni yoo rii pe oṣupa ni baba irawọ. 

No comments:

Post a Comment

Pages