Bi nnkan ṣe n lọ yii afaimọ kawọn oludije kan tajọ eleto idibo gbe orukọ wọn jade ma bara wọn nile ẹjọ laipẹ.
Bi nnkan ṣe n lọ yii afaimọ kawọn oludije kan tajọ eleto idibo gbe orukọ wọn jade ma bara wọn nile ẹjọ laipẹ.Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọpọ wọn ni wọn sọ pe wọn ti dije tẹlẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu kan tẹlẹ amọ ti wọn fo sẹgbẹ oṣelu mi lati tun dije, eyi ti wọn sọ pe o lodi si ofin eleto idibo ti wọn gbe kalẹ.
Ohun ti ofin naa tọdun 2026, to ṣiṣẹ lori 2022, eyi ti wọn pe ni fifo latinu ẹgbẹ oṣelu kan bọ sikeji.
Eleyii ni wọn sọ pe o fofin de oludije kan ninu ẹgbẹ oṣelu to fidi rẹmi lakooko ibo alabẹsekele iyẹn Pamari lati lọọ dije ninu ẹgbẹ oṣelu miiii.
Iru nnkan bẹẹ ni wọn lo ṣẹlẹ bayii pẹlu orukọ oludije tawọn INEC gbe jade, ti wọn lo ti n kọ awọn oloṣelu lominu.
Lara awọn oludije bẹẹ ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, ẹni to ti figba kan dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣugbọn ti ẹgbẹ naa fun Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla tọpọ mọ si Yayi ni tikẹẹti ẹgbẹ naa.
Ko si pẹ sigba naa ni obinrin yii pariwo pe oun ti fẹgbẹ naa silẹ darapọ mọ PDP nipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti fun un tikẹẹti fun ipo sẹnetọ, eyi ti wọn sọ pe o tako ofin eleto idibo.
Akọkọ wọn ni Iyabọ Ọbasannjọ ko bawọn kopa ninu ibo alabẹsekele ẹgbẹ ọhun ti wọn pe ni pamari, bawo waa ni eleto idibo ṣe gbe orukọ ẹ jade gẹgẹ bi oludije fun ipo sẹnetọ.
Ati pe ọpọ igba ni Ọbasanjọ naa ma n sọ pe oun bawọn wa nibẹ nigba ti wọn fa Yayi kalẹ, oun si ni ẹni to kọkọ kii ku oriire, eyi to tumọ si pe o ṣi wa ninu ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bi ọkan lara oludije.
Wọn ni awọn nnkan wọnyii gan an ti to lati ma jẹ ki Iyabọ Ọbasanjọ kopa nibi ibo to n bọ nitori bi ẹni pe o rufin.
Bakan naa ni oludije kan ti wọn pe ni Imọlẹayọ toun naa fidi rẹmi lẹgbẹ oṣelu ADC, amọ torukọ ẹ jade fun ipo sẹnetọ lẹgbẹ oṣelu APM.
Amọ ṣa, ẹnikan to ba wa sọrọ sọ pe orukọ ti INEC ṣi gbe jade, ko tii fọkan awọn oludije naa balẹ nitori ọpọ wọn ni wọn yoo si yọ danu nipaṣẹ ẹhonu tabi ti wọn ba gbe e lọ ile ẹjọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọpọ wọn ni wọn sọ pe wọn ti dije tẹlẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu kan tẹlẹ amọ ti wọn fo sẹgbẹ oṣelu mi lati tun dije, eyi ti wọn sọ pe o lodi si ofin eleto idibo ti wọn gbe kalẹ.
Ohun ti ofin naa tọdun 2026, to ṣiṣẹ lori 2022, eyi ti wọn pe ni fifo latinu ẹgbẹ oṣelu kan bọ sikeji.
Eleyii ni wọn sọ pe o fofin de oludije kan ninu ẹgbẹ oṣelu to fidi rẹmi lakooko ibo alabẹsekele iyẹn Pamari lati lọọ dije ninu ẹgbẹ oṣelu miiii.
Iru nnkan bẹẹ ni wọn lo ṣẹlẹ bayii pẹlu orukọ oludije tawọn INEC gbe jade, ti wọn lo ti n kọ awọn oloṣelu lominu.
Lara awọn oludije bẹẹ ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, ẹni to ti figba kan dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣugbọn ti ẹgbẹ naa fun Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla tọpọ mọ si Yayi ni tikẹẹti ẹgbẹ naa.
Ko si pẹ sigba naa ni obinrin yii pariwo pe oun ti fẹgbẹ naa silẹ darapọ mọ PDP nipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti fun un tikẹẹti fun ipo sẹnetọ, eyi ti wọn sọ pe o tako ofin eleto idibo.
Akọkọ wọn ni Iyabọ Ọbasannjọ ko bawọn kopa ninu ibo alabẹsekele ẹgbẹ ọhun ti wọn pe ni pamari, bawo waa ni eleto idibo ṣe gbe orukọ ẹ jade gẹgẹ bi oludije fun ipo sẹnetọ.
Ati pe ọpọ igba ni Ọbasanjọ naa ma n sọ pe oun bawọn wa nibẹ nigba ti wọn fa Yayi kalẹ, oun si ni ẹni to kọkọ kii ku oriire, eyi to tumọ si pe o ṣi wa ninu ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bi ọkan lara oludije.
Wọn ni awọn nnkan wọnyii gan an ti to lati ma jẹ ki Iyabọ Ọbasanjọ kopa nibi ibo to n bọ nitori bi ẹni pe o rufin.
Bakan naa ni oludije kan ti wọn pe ni Imọlẹayọ toun naa fidi rẹmi lẹgbẹ oṣelu ADC, amọ torukọ ẹ jade fun ipo sẹnetọ lẹgbẹ oṣelu APM.
Amọ ṣa, ẹnikan to ba wa sọrọ sọ pe orukọ ti INEC ṣi gbe jade, ko tii fọkan awọn oludije naa balẹ nitori ọpọ wọn ni wọn yoo si yọ danu nipaṣẹ ẹhonu tabi ti wọn ba gbe e lọ ile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment