Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti bu ẹnu atẹ lu bi iṣakoṣo Aarẹ orileede yii, iyẹn Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ṣe mu ifasẹyin ba ọrọ aje, eyi to ni o jẹ kijọba rẹ kuna lati bi ọdun mẹta abọ sẹyin to ti gbakoso.
O sọrọ yii ninu eyi ti Ọgbẹni Babatunde Tijani, ọkan lara agba ẹgbẹ Allied Progresive Movement, APM, jẹ lorukọ Gomina, nibi ayẹyẹ iṣafihan igbakeji oludije Gomina, Arabinrin Abọsẹde Akinlade atawọn oludije fun ile igbimọ aṣofin agba,aṣoju ṣofin ati ile igbimọ aṣofin tipinlẹ, to waye lonii,ọjọ Aje, niluu Abẹokuta .
Gomina ṣalaye pe latọjọ ti alaye ti daye, ko si orileede naa idojukọ onibeji ọrọ aje eyi ti ẹgbẹ oṣelu APC fi le lẹ yii.
O ni bawo ni ẹnikan yoo kan ji ti yoo paṣẹ iyọkuro afikun owo epo iyẹn sọbsidi, lai kọkọ wa ọna abayọ ti yoo di alafo.
Makinde tun ni iyẹn ko ti tan an nilẹ ti wahala ọrọ owo naira wa tun tẹle, awọn nnkan meji to ni o ṣe pataki ni wọn fi mu igbe aye le koko fawọn araalu.
O ni awọn nnkan meji yii ko orileede naa lagbaaye to le samuyọ ẹ lẹẹkan naa. O waa sọ pataki nnkan tawọn ṣe lonii yii ni lati jẹ kawọn eeyan ipinlẹ Ogun mọ pe ẹgbẹ oṣelu APM ti balẹ gudẹ sipinlẹ ọhun.
O ni awọn ti n sọ fawọn eeyan ki wọn bẹrẹ si nii polongo ẹgbẹ naa kaakiri, nitori awọn ti ṣetan lati mu awọn araalu kuro ninu igbe aye inira.
O wa fi akoko yii parọwa sawọn ọmọ ẹgbẹ APM nipinlẹ Ogun lati wa ni iṣọkan ati ifẹ, ki wọn si rii pe awọn araalu n rọ wọnu ẹgbẹ naa.
Ninu ọrọ Rotimi Babajide oludije fun ipo Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APM, o sọ pe akoko ti fawọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun latii lo kaadi idibo wọn fi le ẹgbẹ oṣelu APC danu.
O sọ pe ọmọ ojulowo ipinlẹ Ogun ti wọn le tọpaṣẹ ibi toun ti ṣẹ wa. Ati pe pẹlu idaniloju oun yoo jawe olubori nibi ibo to n bọ naa.
Nigba ti alaga ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Abayọmi Sanyaolu sọrọ, oun naa sọ pe bi wọn ba ni ki oun fun ijọba to wa lode yii ni igbelewọn lori iṣakoso wọn, o loun fun wọn ni marundinlogoji, nitori pe wọn ko ṣe daadaa rara, wọn si ti mu ijakulẹ ba araalu.
O wa rọ awọn araalu ki wọn yẹra fun tita ibo wọn nitori ko le so eṣo rere fawọn gan an funra wọn.
No comments:
Post a Comment