Ṣe ni Ṣalisu kan lọọ fi akoko awọn agbegbe Ogun Central ṣofo niluu Abuja- Oludije Sẹnetọ ADC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 12 August 2026

Ṣe ni Ṣalisu kan lọọ fi akoko awọn agbegbe Ogun Central ṣofo niluu Abuja- Oludije Sẹnetọ ADC




Ọnarebu Samuel Oluwafẹmi Abiọdun Oni, oludije fun ipo sẹnetọ fagbegbe Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti sọ pe bigba ti ẹni to jẹ aṣoju wọn bayii kan lọọ fi akoko ṣofo ni lati nnkan bi ọdun mẹta ataabọ to ti wa nibẹ, nitori ko si nnkan pato to le sọ pe abọ gidi ree fawọn eeyan  rẹ.

Oludije naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe to ba dabi irọ, kia lọ sigboro awọn agbegbe ọhun lati beere lọwọ awọn araalu.

O sọ pe gbogbo awọn aṣiṣe yii loun yoo mu kuro bi wọn ba le dibo foun ninu ibo ti yoo waye lọdun 2027.


Fẹmi Oni tun fi kun ọrọ ẹ pe, "Nipa ti Salisu, ẹ jẹ ka jọ bọ sigboro ka beere lọwọ araalu ọdun mẹrin to n ṣe lọọ yii, ko wa tọka sawọn nnkan to ṣe fun wọn.

"Aarin gbungbun Ogun n fẹ aṣoju gidi, ki i ṣe bi ti Salisu to fi akoko ọdun mẹrin ṣofo fawọn eeyan agbegbe naa, nitori emi funra mi, mi o rii nnkan to gbe ṣe fawọn araalu to ṣoju fun.

Ọrọ ẹnikan lo maa n jẹ irọ, ẹyin ẹ lọ sigbooro, ki ẹ beere lọwọ araalu.  Bakan naa lo sọ pe oun ko ri Iyabọ Ọbasanjọ toun naa jade dupo sẹnetọ ni ẹkun kan naa labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, bi ẹni to fẹẹ jade dupo.

Gẹgẹ bo ṣe wi, "Emi o ri Iyabọ Ọbasanjọ gẹgẹ bi ẹni to n dije, nitori ti eeyan ba sọ pe oun fẹran araalu, to lọ lati bii ọdun mẹẹẹdogun, to lọ ti ko pada wẹyin wo, to waa de lakooko yii to loun tun fẹẹ jade  dupo, iyooku ku sọwọ araalu.

"ibeere to yẹ ki a maa beere lọwọ ẹ ni pe ṣe ifẹ araalu lo ni tabi tara ẹ, loootọ o ṣe daadaa fawọn akoko to lo, amọ ṣa, awọn Yoruba sọ pe taa ba ran ọmọ nileewe, to ṣe daadaa diẹ, ẹ jẹ ka tun ran ẹlomii lọ, iyẹn tun le ṣe daadaa julọ.

"Ẹni to ti lọ lati ọdun kẹẹdogun to ṣẹṣẹ n beere nọmba foonu awọn to ti fi silẹ, ẹlomii to ba pe a sọ pe mo ṣẹṣẹ gba nọmba yin lọwọ lagbaja.

"Iyẹn ku sọwọ araalu ati pe ibeere kan ti mo fẹẹ ki ẹ beere lọwọ ẹ ni pe ẹṣẹ wo ni mẹkunnu fi ṣẹ wọn ti wọn ko fẹẹ ki wọn gberi.

"Baba ẹ ti ṣe aarẹ ọdun mẹjọ, oun naa tun ṣe aṣofin ọdun mẹrin, kin ni nnkan to gbagbe to n wa.

Ọkunrin naa to wa lati ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode tun sọ pe o ti pẹ to ti wu oun lọkan lati sin awọn eeyan oun.

Ṣugbọn lọjọ kan ni ẹmi Ọlọrun dari oun pe ki oun lọ sinu iwe bibeli, ki oun lọọ ka 
iwe keji Nehemaih,oun ka a, oye to ye oun nibẹ ni pe Oluwa ran oun niṣẹ lati lọọ ṣoju awọn eeyan oun

O sọ pe, "Ni orileede yii gbogbo wa la ri ibi taa ba ara wa, ipo ti eto abo wa nigba kan ko ri bayii tẹlẹ. Eeyan le duro niwaju ile ẹ ko sun, amọ ti ko ri bẹẹ mọ laye ode oni.

"Ohun to si faa ni pe ọpọ awọn taa yan sipo wọn ko ba ti araalu lọ, apo ara wọn ni wọn n ja fun.

"Erongba temi ni pe taa ba de ọhun, a le ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn yooku ọna ti eto abo yoo ṣe rinlẹ.

"A o ri pe nigba kan ti olori orileede yii fi n dupo o ṣeleri ina fun wa ti ko ni jẹ wa niya, oun yoo ṣe igba oun yoo ṣe awo, amọ to jẹ pe irọ ni gbogbo ẹ. Nitori pe nigba ti wọn yoo debẹ, nnkan ti wọn sọ kọ ni wọn n ṣe.

"Akọkọ aba mi ni pe gbogbo wa la mọ bi orileede ṣe n lọ, nnkan ko ri bo ṣe yẹ ko ri, iyẹn lo n gbe wa ninu lati dije, ki Oluwa ko kọ waa ṣe ki mudunmudun oṣelu le dele doko, ko ma jẹ pe awọn kan ni yoo maa ko gbogbo anfaani ẹ.

Bẹẹ  lo tun ṣalaye pe, "Ipinnu mi fawọn araalu pọ, lakooko yii ko si ina, awọn eeyan ko sọrọ nipa iyẹn mọ, ka jade layọ, ka pada dele layọ ni wọn sọ, nitori abo, bẹẹ naa ko si ọna, laye ọjọun towo wọle fawọn ijọba ibilẹ, wọn a ṣe ọna lọ kaakiri abule, ko siyẹn mọ, ọna igboro nikan ni wọn n ṣe.

"Eto wa fawọn ọdọ atawọn oṣiṣẹ fẹyinti, ko yẹ ki wọn ma la kaka ninu ile, bẹẹ ni eto tun wa fawọn akanda, mi o tiẹ ribi tijọba ti fọwọ ba wọn rara.

Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC wa gba awọn araalu nimọran pe ki wọn ma ni lọkan pe ibo tiwọn di kọ ni wọn n ka, oun ni wọn yoo ka.

"Ṣe ẹ ri awa araalu gan an la n fi aye jibiti silẹ, nibi tawọn igba eeyan ti forukọ silẹ kawọn bi ogun ba wa dibo, a ti fi aye ole silẹ fun wọn.

"Amọ nibi tawọn igba ti forukọ silẹ kawọn ọgọsan jade dibo nibẹ, ti wọn ba fẹẹ jale, ko le ju mẹwaa lọ, nitori ijọba to wa loke  a fẹẹ lo ọwọ agbara.

"Ki awọn araalu ṣaanu ara wọn atawọn ọmọ wọn pẹlu.Ki wọn ye ta ọjọ ọla wọn fọdun mẹrin, ẹ wo nnkan to n ṣẹlẹ ni Ọṣun ti wọn fun wọn ni irẹsi kongo meji ati ẹgbẹrun marun un  naira ti wọn si tun gbe wọn ṣepe ti wọn ko ba dibo fun wọn.

"Ṣe owo ati irẹsi yẹn ni wọn yoo fi ṣe ọna to yẹ ki wọn ṣe, ẹyin naa kuku mọ ibi ti wọn ba wa de, wọn a wa, wọn a tun parọ fun wa.

"Ẹ ma jẹ ka tori owo tabi irẹsi lọọ dibo, ki a dibo fun aṣoju to maa nifẹẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages