Ẹgbẹ ọdọ Agbado Youth Forum nilẹ yii ati ni oke okun ti ranṣẹ ikinni ku oriire ṣi Iyalode ilu Agbado, Oloye Ayọka Agboke lori bi wọn ṣe sọ ọ di iyalode gbogboogbo iyẹn jẹnẹra nijọba ibilẹ Ifọ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Oliyide Sunday, akọwe ẹgbẹ fi sita ni wọn ti fi idunnu wọn han lori agbega nla to deba Iyalode Ayọka Agboke ọhun ti wọn si ba a ṣajọyọ.
Laipẹ yii ni awọn igbimọ lọbalọba tijọba Ifọ lẹta ranṣẹ si obinrin naa nibi ti wọn ti yan an gẹgẹ bi iyalode gbogboogbo, eyi ti Ọba Sulaiman Adekunle Bamgbade Ayọdele, Ọlọfin tiluu Iṣhẹri fọwọ si lorukọ igbimọ lọbalọba ọhun.
Nibẹ ni wọn ti kan sara sii sawọn akitiyan ẹ nigba to ṣakoso gẹgẹ iyalode Agbado gẹgẹ bi akọni obinrin to si ti mu idagbasoke ba ilu naa, tawọn si nigbagbọ pe yoo tẹsiwaju lakooko to di Iyalode jẹnera bayii.
Ko si pẹ ti lẹta tun fi jade lati ọdọ Ọnarebu Idris Ọlalekan Kusimọ, alaga ijọba ibilẹ Ifọ, nibi to ti fọwọ si fifi Ayọka Agboke jẹ Iyalode jẹnẹra.
Ninu lẹta loun naa ti sọ pe oun nigbagbọ pe bawọn ọba alaye ọhun ṣe yan Iyalode jẹnẹra yoo tubọ mu isọkan, ifẹ ati alaafia ba gbogbo igbimọ lọbalọba ati ijọba ibilẹ lapapọ.
Bi iroyin oriire yii ṣe gba igboro lẹgbẹ awọn ọdọ iyẹn Agbado Youth Forum ti ba iyalọja jẹnera naa yọ.
Bẹẹ ni wọn lo akoko naa lati fi ẹmi imoore wọn han si alaga Ijọba ibilẹ Ifọ, Ọnarebu Kuṣimọ lori bo ṣe fọwọ si igbesẹ naa.
Wọn ni eyi tumọ si irẹpọ to danmọran wa laarin wọn ati ọba alaye ati oun naa nigbagbọ ninu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.
Bakan naa ni wọn tun dupẹ lọwọ Ọlọfin tilu Iṣhẹri, Ọba Sulaiman Adekunle Bamgbade Ayọdele, atawọn ọba alaye yooku nijọba ibilẹ Ifọ, lori igbesẹ iyalode jẹnera.
Wọn tun fẹmi imoore wọn han si awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ẹkun Ifọ Kin in ni ati keji pẹlu.
Lapaapọ wọn ki gbogbo ọmọ Agbado nile loko ku oriire ayọ to deba wọn ọhun.Wọn ni igba Iyalode Jẹnẹra Ayọka Agboke yoo tu gbogbo wọn lara.
Congratulations grandma
ReplyDelete