Makinde Fasunle ati iyawo ẹ di Gbọbaniyi ati Yeye Gbọbaniyi Orile-Itafin nipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 5 August 2026

Makinde Fasunle ati iyawo ẹ di Gbọbaniyi ati Yeye Gbọbaniyi Orile-Itafin nipinle Ogun

Ohun ayọ ati idunnu lo waye ni afin Orile-Itafin, Abẹokuta nipinlẹ Ogun, nigba ti Ọba Mọruf Alani Ọlalekan Adebayọ, Onitafin ti Orile Itafin fu agba sọrọsọrọ nni Oloye Makinde Fasunle tọpọ mọ si Sẹnetọ ati iyawo ẹ, Azeezat, joye nla.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ayẹyẹ ifinijoye Gbọbaniyi ati Yeye Gbọbaniyii ọhun waye ni afin Orile- Itafin.

Ayẹyẹ ifinijoye ọhun ni wọn fi sami ayẹyẹ ọjọọbi aadọrun ọdun ti Ọba Adebayọ dele aye.

Ko to di pe ifinijoye ọhun waye ni wọn kọkọ ṣadura nilana musulumi fun ti ọjọọbi ọba,nibi tawọn araalu ti peju pesẹ.

Lẹyin naa ni wọn jawe oye le Makinde Fasunle ati iyawo ẹ lori, ti wọn si ṣadura fun wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn ipa pataki ti Gbọbaniyi ati Yeye Gbọbaniyi ti ko lawujọ paapaa riran awọn alaini lọwọ lori awọn eto to n ṣe.

Bakan naa wọn ni gbajumọ sọrọsọrọ naa tun jẹ ọkan lara awọn to nifẹẹ si aṣa ati ede Yoruba, to si jẹ pe o ti mu igbega baa lọpọ igba.


Ninu ọrọ Oloye tuntun ọhun lo ti dupẹ lọwọ Onitafin ti Orile-Itafin,Ọba Adebayọ lori bi wọn ṣe ro ohun rere roo nipa oye tuntun naa.

O waa ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo ma sa lati ṣatilẹyin fun ilu naa.

Lara awọn eeyan pataki to tẹle Gbọbaniyi Orile- Itafin waa joye ni Alaaji Wale Ẹniọla, oludasilẹ ileeṣẹ Global Wale Estate, Oloye Oluṣẹgun Ogunjinmi, Atayeṣe ilu Ikọpa, to tun jẹ oludasilẹ ootẹli Five Star, Oloye AbdulWakeel Adeṣina Bello,Akingbayi ilu Ikọpa.

No comments:

Post a Comment

Pages