Gọngọ sọ lọjọ ti wọn jawe oye Asiwaju Yeye Oge le Fọlakẹ Adunni Adeyẹmi lori ni Orile- Itafin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 5 August 2026

Gọngọ sọ lọjọ ti wọn jawe oye Asiwaju Yeye Oge le Fọlakẹ Adunni Adeyẹmi lori ni Orile- Itafin

Ẹṣẹ o gbero ni afin Onitafin ti Orile Itafin, to wa ni Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, nigba ti Ọba ilu naa, Ọba Mọrufu Alani Ọlalekan Adebayọ, fi agba oniroyin obinrin nni, Fọlakẹ Adunni Adeyẹmi joye Aṣiwaju Yeye Oge.

ifinijoye ọhun lo waye lati fi ṣami ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin ọdun ti Ọba naa dele aye, eyi ti wọn fodidi ọjọ mẹrin silẹ fawọn eto loriṣiriṣi.

Lara eto ọhun ni wọn ti fi Fọlakẹ joye ọhun, nibi tawọn mọlẹbi, ara ati ọrẹ to fi mọ awọn oniroyin akẹgbẹ ẹ ti wa baa ṣajọyọ oye tuntun naa.
Ọba naa ṣapejuwe Aṣiwaju Yeye Oge yii gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu, to si laapọn, ti wọn lo si tun lọyaya pẹlu.

Wọn ni ọpọ awọn nnkan ribiribi lo ti ba wọn lọwọ si fun idagbasoke ilu Orile- Itafin, ko to di pe o joye ọhun.

Kabiyesi waa gbadura fun un pe yoo ri ẹmi lo oye naa ati pe lakooko to joye ilu naa yoo tubọ maa gberu si.

No comments:

Post a Comment

Pages