Ki i ṣe tuntun mọ pe Ọnarebu Rotimi Geroge Taylor ni ẹgbẹ oṣelu Nigerian Democratic Congress iyẹn NDC fun ni tikẹẹti oludije fun ipo sẹnetọ fun ẹkun Ogun Central.
Ṣugbọn latigba ti ariwo ọkunrin naa ti jade ni ibẹrubojo ti n deba awọn oludije kan nitori wọn mọ pe Rotimi ko ṣee fọwọ rọ sẹyin nidii agbo oṣelu.
Idi ni pe wọn mọ pe ọlọpọlọ pipe ni Rotimi George Taylor ti wọn ba n sọrọ nipa oṣelu, ẹni tawọn araalu n ṣe tiẹ ni, nitori awọn akọsilẹ rere to ti ni jakejado orileede yii lawọn ipo to ti di mu.
Bi ki i ba ṣe bi wọn ṣe lo ọwọ ọla ninu ibo to kọja lọdun 2023, ọpọ awọn eeyan agbegbe Ọbafẹmi Owode/Abeokuta North/Ọdẹda lọ mọ pe ọkunrin yii lo jawe olubori nigba to dupo aṣoju-ṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour.
Ohun to tun jẹ ki awọn araalu fi n sọ pe lọtẹ yii o, Rotimi lọ gbọdọ lọọ ṣoju wọn ni ẹkun Ogun Central ninu ibo to n bọ ni bi ifẹ ọmọniyan ṣe jẹ ẹ logun, ti gbogbo mutumuwa yoo si maa gbe igbe aye to rọrun.
Ẹgbẹ oṣelu NDC ipinlẹ Ogun mo pe oludije wọn yii kaju ẹ, nitori ẹ ni wọn ṣe fun un ni tikẹẹti, ti wọn si nigbẹkẹle ninu ẹ pe yoo mu esi rere jade wa.
Ọpọ awọn oludije tawọn ẹgbẹ oṣelu yooku gbe dide lọkan wọn ko balẹ nitori wọn mọ pe ọmọ George-Taylor, ko ṣee fojudi
Awọn ti wọn ti roo lọkan pe ko ni si wahala fun wọn ninu ibo to n bọ ni Rotimi ẹgbẹ oṣelu NDC ti n ja laya ti wọn mọ pe ko rọrun fawọn.
Ọrọ kan soso ti Rotimi maa sọ tawọn agba gba pe ijinlẹ ni pe, "Ẹ jẹ ki awọn araalu dibo fun ẹri ọkan wọn, tijọba to wa lode yii ba tẹ yin lọrun, ẹ le dibo fun wọn, ṣugbọn ti ko ba tẹ yin lọrun, ti ẹ n wa atunṣe, ẹ le tẹle wa,
Awọn kan tun wa sọ pe iya bọ, Ọlọrun ko ni jẹ ka tun jiya nipinlẹ Ogun, iya kankan ko le wa, irọrun ati ayọ lo n bọ"
Ẹ gbọ naa, ta lo fẹẹ kiya tun jẹ oun ni Ogun Central, ko si o, gbogbo eleyii ni Rotimi fi di ẹru jẹjẹ ti wọn ko mọ ọna ti yoo gba yọ si wọn.
No comments:
Post a Comment