A ṣeto idije ere bọọlu fawọn ọmọleewe fun ilanilọyẹ ewu nidii iṣẹ fayawọ- Afẹni - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 14 July 2026

A ṣeto idije ere bọọlu fawọn ọmọleewe fun ilanilọyẹ ewu nidii iṣẹ fayawọ- Afẹni

Ọga agba fẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Kayọde Afẹni, ti sọ pe idi pataki ti wọn fi ṣagbekalẹ idije ere bọọlu fawọn ọmọleewe ni fun ilanilọyẹ lati le mọ ewu to wa nidii iṣẹ fayawọ, ati bi wọn ṣe le ṣa fun un patapata.

O sọrọ yii lakooko ti wọn ti wọn ṣi idije ọhun eyi ti wọn pe ni Afẹni 2026, eyi tileeṣẹ aṣọbode naa ṣe pẹlu ajọṣepọ  Ileẹkọ, Jonnyyeko College of Health Science and Technology,

Ọga agba naa tun ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi owe Yoruba kan to sọ pe ati kekere ni musulumi ti n kọ ọmọ ẹ ni asọ̀. Idi niyii to fi jẹ pe lati ileewe lo yẹ ki wọn ti maa tẹ mọ wọn leti pe fayawọ ki i ṣe iṣẹ ti wọn le maa ni lọkan lati ṣe lọjọ iwaju.

O  ni, " igbagbọ ti wa ni peti wọn ba mọ pe awọn le gbà bọọlu la nigba ti wọn  wa ni kekere, o maa ran wọn lọwọ lati fi ṣe afojusun wọn, ki wọn ma ba ya sidi iṣẹ ti ko bofin mu rara".

Idije naa ni awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejila ninu ti gbogbo ọmọleewe ti wọn yoo kopa nibẹ jẹ ọgọrun-un

 Ẹbùn ńlá, títí kan àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ àti owó, lo ti wa nilẹ fún àwọn tó ba borí ninu idije naa .

Idije naa to ti bẹrẹ lọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2026  ni yoo pari ni lọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2026.



No comments:

Post a Comment

Pages