Bo tilẹ jẹ ṣe lawọn to gbọ igbesẹ tuntun tileṣẹ ọhun gbe lo n bi ara wọn leere pe igba wo lawọn alakoso roo pe o yẹ ki wọn yi orukọ wọn pada.
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita lọjọ Aiku,wọn jẹ ko di mimọ pe ayipada naa pọn dandan pẹlu bi awọn onipin idokoowo tuntun ṣe gba akoso nipa agbekalẹ ati ilana tuntun.
Nigba to n sọrọ, alakoso agba ileeṣẹ naa, Lolu Alade-Akinyẹmi jẹ ko di mimọ pe igba ọtun lo bẹrẹ bayii, nipasẹ afojusun ati agbekalẹ ọtun, eyi ti yoo tubọ jẹ ki wọn gbilẹ sii nipa okoowo ṣiṣe.
Bakan naa, alaga igbimọ iṣakoso ileeṣẹ HBM Nigeria Plc, Gbenga Oyebọde fidi rẹ mulẹ pe ayipada ọtun yii ni awọn ṣagbekalẹ rẹ lojuna lati tubọ duro lori awọn aṣeyọri ati ilana ti wọn fi n lọ siwaju loorekoore.
No comments:
Post a Comment