Ọna mii lo tun gbsyọ bayii, nitori bawọn kan ninu ẹgbẹ ọhun ṣe kọ lẹta ẹhonu wọn han si alaga ẹgbẹ naa lapapọ lati ṣewadii lori awọn ẹsun kan ti wọn fi kan alaga wọn, Ọtunba Fẹmi Patirck Ṣoluade.
Gẹgẹ iwe ti wọn fi sọwọ si wa ni wọn ti rọ alaga ẹgbẹ naa lapapọ lati wọdi alaga ẹgbẹ wọn yii lati ṣalaye ara ẹ.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe, ko wa sọ nipa bo ṣe n ṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu latigba ti Itunu Abioro, to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ ti fi ipo silẹ.
Wọn sọ pe awọn fẹẹ mọ nipa bo ṣe n ṣe owo ẹgbẹ ọhun to wa ni Steirling bank, wọn lawọn fẹẹ mọ boya alaga wọn yii nawo ọhun lọna tooto tabi o da ijọba tara ẹ ṣe lee lori.
Bẹẹ ni wọn tun fẹsun kan an pe ṣe lo yọ awọn yooku, ti wọn gbọdọ kọwọ bọwe owo ni banki kuro la jẹ ki ẹgbẹ mọ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun tun fẹsun kan alaga wọn yii pe, latigba to ti dori ipo to wa yii lo ti n ṣiwa wu sawọn ọmọ ẹgbẹ, ti wọn lo n lo agbara le wọn lori.
Wọn ni eyi to buru ju nibẹ ni bo ṣe yẹyẹ igbakeji ẹ nita gbangba nibi ayẹyẹ kan to si jẹ pe latigba naa ni ara onitọhun ko ti ya, ti aisan rọpa rọsẹ si n yọ ọ lẹnu titi di akoko yii.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pẹ awọn ko le sọ pato okunfa aisan igbakeji ẹ yii amọ ko le ṣe lẹyin bi Soluade ṣe ba a ja nita gbangba.
Bẹẹ ni wọn sọ pe ọpọ owo awọn oludije lo dari sinu akaunti ẹ, ti ko jẹ ki wọn ṣan si apo oṣuwọn ẹgbẹ.
Wọn ni iwadii tawọn ṣe to fẹsẹmulẹ jẹ ki wọn mọ pe o kere tan awọn oludije mẹwaa ti wọn fi ipinnu wọn han lo ni ki wọn sanwo sinu apo isuwọn ẹ, to si jẹ pẹ ti ẹgbẹ lo yẹ ki wọn san si.
Bẹẹ ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ọkan lara awọn to sanwo sinu akaunti Olufẹmi Patrick Soluade, wa pẹlu iwe to fi sanwo tiyẹn si duro bii ẹri nla tawọn le ko silẹ fun alagẹ ẹgbẹ lapapọ lati ṣewadii lee lori.
Bakan naa lawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ṣalaye siwaju pe ẹdun ọkan lo jẹ lori bi alaga yii ṣe yii ṣe n huwa aitọ sawọn obinrin paapaa awọn to jade dupo, to si n ṣe wọn baṣubaṣu
Wọn ni ti akoko ba to awọn obinrin tọrọ naa kan yoo jade sita pẹlu awọn ẹri ti wọn ni lọwọ.
Wọn ni ninu oṣu keji ọdun yii lawọn ti kọkọ jawe gbele ẹ fun Fẹmi Ṣoluade ṣugbọn ti wọn pada yanju ẹ lẹyin ti Ọnarebu Dimeji Fabiyi atawọn ọmọ ẹgbẹ kan da si ọrọ naa.
Awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun wa rawọ ẹbẹ si awọn olori wọn niluu Abuja lati bawọn ṣewadii finnifini ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ le e lori.
Wọn rọ wọn lati gbe awọn igbimọ kọọkan dide, lati ṣe iwadii lori awọn ẹsun ti wọn fi kan alaga wọn, to fi mọ awọn to mọ nipa ayẹwo owo, ki wọn si ri okodoro di mu.
Awọn to fọwọ si lẹta ẹhonu ọhun ni Hudus Dubaja Idris,Ismaila Adejumọ, Temitọpẹ Adebayọ ati Raṣidat Yẹkinni.
Amọ sa, Ọgbẹni Adebayọ Yunus, to jẹ ti ikọ Fẹmi Ṣoluade ti fesi pe gbogbo ẹsun ti wọn fi kan alaa wọn ko lẹsẹ nilẹ ati pe iṣẹ oṣelu ni
.
Ninu atẹranṣẹ to fi sọwọ si wa lalẹ yii lo ti sọ pe lootọ ni wọn le fẹsun kan eeyan nidii oṣelu, ṣugbọn eyi to ṣe pataki ni lati ri aridaju ati koko ninu ẹ.
O fikun ọrọ ẹ pe nnkan pataki tawọn ọmọ ẹgbẹ ADC ipinlẹ Ogun n fẹ ni bi ayipada rere yoo ṣe bọjọ iwaju wọn ti ẹgbẹ ọhun yoo tun fi gbooro si
Bẹẹ lo sọ pe lsipẹ yii ni gbogbo alaga ẹgbẹ lawọn ijọba ibilẹ jade sita ti wọn fi igbagbọ wọn han si alaga wọn yii.
No comments:
Post a Comment