Yayi ko le ṣẹru ba mi, emi gan an ni mo maa ja a laya- Oludije Gomina APM. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 29 May 2026

Yayi ko le ṣẹru ba mi, emi gan an ni mo maa ja a laya- Oludije Gomina APM.

Oludije Gomina lẹgbẹ oṣelu APM nipinlẹ Ogun, Oluwarotimi Babajide ti sọ pe oun ko ri ti oludije akẹgbẹ ẹ lati APC, Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla Yayi ro rara nipa ti ibo gomina ọdun to n bọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o loun gan an ni oun duro bii ẹru ati ijaya fun, nitori ṣe ni ọkan oun balẹ pe oun yoo jawe olubori.

O sọrọ ọhun nibi ibo abẹle ẹgbẹ naa to waye lọjọ Abamẹta, Satide, nibi ti wọn ti faa kalẹ gẹgẹ bi oludije wọn.

Babajide dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ onipaki iyẹn APM tipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe foun ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina.

O ṣeleri pe iṣeto ijọba oun ti wọn ba fi le dibo yan oun wọle lọdun 2027, yoo tu gbogbo awọn araalu lọrun pẹlu awọn eto toun ti la kalẹ.

O tẹsiwaju pe inu oun dun pe ala toun ti n la ti waa di imuṣẹ nipa lati jade dupo di gomina nipinlẹ Ogun.

Babajide tun sọ pe gbogbo bi ijọba oun ba ṣe n lọ, loun yoo ma fi to araalu leti, ati pe ko si adaṣe ninu ijọba oun.

O ṣalaye siwaju pe awọn ohun imayedẹrun idagbasoke tijọba ẹ yoo ṣe lawọn ẹlẹkajẹka bii ọgbin, eto ẹkọ, ọrọ aje atawọn mii in ni eyi ti araalu yoo lawọn ipa pataki lati ko.

Lakooko to n dahun awọn ibeere lati ọdọ awọn oniroyin lo ti la mọlẹ pe oun ko ri ẹnikankan bi ẹru tabi ijaya ninu awọn ti wọn jọ n dije, o loun gan an loun jẹ ẹru fun wọn.

Ninu ọrọ Ọnarebu Idowu Imọlẹayọ, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba lo ti gba awọn araalu niyanju lati sọra fun tita ibo wọn. Nitori oun mọ pe gbogbo ogo ni yoo jẹ ti Ọlọrun. 

O ni awọn mọ pe awọn ko lowo bi ẹgbẹ oṣẹlu kan amọ awọn ti wa ni imurasilẹ pẹlu idaniloju pe wọn yoo jawe olubori.

Ninu ọrọ Abayọmi Sanyaolu, alaga ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun lo ti sọ pe oun nigbagbọ pe ẹgbẹ wọn yoo wọle lọdun 2027.

O sọ pe ko si awitunwi mọ, APM ti wa ni igbaradi, o ni ibo to n bọ ko le ṣe e nipa ti owo tabi ero bi ko ṣe bi oludije ṣe mọ eeyan si pẹlu atilẹyin lati ọdọ Ọlọrun.

O wa ṣapejuwe oludije wọn gẹgẹ bi ọmọ onilẹ, ti wọn ko le wa iṣẹdalẹ wọn ti, o ni Aribajo, Awekoro lo ti wa ati pe ẹni to mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ ni.

No comments:

Post a Comment

Pages