Ero rẹpẹtẹ nibi ayẹyẹ iranti ogun Tọba Ọpalẹyẹ to Kasnanty ṣagbekalẹ ẹ l'Abẹokuta. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 1 May 2026

Ero rẹpẹtẹ nibi ayẹyẹ iranti ogun Tọba Ọpalẹyẹ to Kasnanty ṣagbekalẹ ẹ l'Abẹokuta.

Johnson Akinpẹlu

Ko sẹni to debi ayẹyẹ iranti ogun ọdun ti Oloogbe Tọba Ọpalẹyẹ, agba sọrọsọrọ jade laye ti ori ẹ ko wu, nigba ti wọn sọ awọn ipa ribiribi ti ọkunrin naa ko.

Ayẹyẹ  ọhun to waye ni gbọngan Continental Suite, Ibara, niluu Abẹokuta ni ko gba ero nibi tawọn eeyan jakanjakan ti peju pesẹ.

Bi awọn sọrọsọrọ ti wọn mọ ọkunrin naa, atawọn ọrẹ ṣe wa nibẹ bẹẹ lawọn ti Tọba Ọpalẹyẹ t ṣe oore fun nsa ko gbẹyin,ti awọn ẹbi ẹ naa ṣi wa lori ijokoo.

Gbajmọ sọrọsọrọ nni ti eto ẹ tun ma n da yatọ lori afẹfẹ, Kọlawọle Adejojo tawon oloolufẹ ẹ nọ si Kasnanty lo ṣagbekalẹ  syẹyẹ naa lati fi bu ọla fun ẹni to pe ni ọga, ọga ẹ yii.

A o ranti pe ni Ọgbọnjọ,oṣu kẹrin, ọdun 2006, ni Oloogbe Tọba Ọpalẹyẹ jade laye nigba ti wọn sin in lọjọ kin in ni, oṣu karun-un, ọdun naa.

Nibi ayẹyẹ ọhun lawọn eeyan bii MC Murphy, Yẹmi Ṣonde, Jimọh Lateef, Johnson Onifade, Busayọ Ọlaifa,Jossy atawọn mii in.
Ninu ọrọ Kọlawọle Adejojo, iyẹn Kasnanty to ṣagbekalẹ eto ayẹyẹ ọhun lo ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn wa fun iranti akọni sọrọsọrọ naa.

O ṣalaye pe ko si bi oun ṣe le kọ itan igbesi aye, ki oun maa fi Tọba Ọpalẹyẹ si,  bo tilẹ jẹ pe ọga ọga lo jẹ si oun

O tan imọlẹ si pe ọga ounYẹmi Ṣonde lo kọ iṣẹ lọdọ Tọba Ọpalẹyẹ bẹẹ lo tun ṣalaye siwaju pe awọn iṣẹ ti Oloogbe naa ti ṣe ko to faye silẹ, ko si eyi to ṣe e fọwọ rọ sẹyin.

Kasnanty tun fikun ọrọ ẹ pe bi eeyan ṣe le maa ranti ẹni to wa laaye bẹẹ lo yẹ ki wọn maa ranti ẹni to ti ku.

Ninu ọrọ Yẹmi Ṣonde, o sọ pe ọga to n fẹẹ ki ọmọọṣẹ ẹ julọ ni Tọba Ọpalẹyẹ.O mẹnuba bo ṣe pade ọga ẹ yii to fi digba to fi kọṣẹ lọdọ ẹ.

O sọ pe gbogbo tifuntẹdọ iṣẹ sọrọsọrọ lo kọ oun to si di iwulo nla foun.Bẹẹ lo sọ pe o ku ọla ti Tọba maa jade laye, toun lọọ woo, bi oun ṣe fẹẹ maa lọ lo pe oun pada pe Akanni nlọ.

Ṣonde ni oun roo pe awada ni toun si sọ pe ko lọ sibi kankan, o maa pẹ fawọn sibẹ lo ni o tẹnumọ to si sọ pe ibi toun ba ṣẹ de kawọn to ku tẹsowaju.

Ninu Iyaafin Anikẹ Ọpalẹyẹ to jẹ iyawo oloogbe naa, o dupẹ lọwọ awọn to ṣagbekalẹ eto ọhun.

Bẹẹ lo fi imoore ẹ han si Yẹmi Ṣonde ati Kasnanty fawọn ipa ti wọn ti ko ṣẹyin latigba ti ọkọ ẹ ti ku.

No comments:

Post a Comment

Pages