Awọn ọdọ Rẹmo North lawọn ko fẹ Adelẹyẹ ti wọn mu bi oludije, wọn lo ti ba oju ẹgbẹ jẹ jinna. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 2 May 2026

Awọn ọdọ Rẹmo North lawọn ko fẹ Adelẹyẹ ti wọn mu bi oludije, wọn lo ti ba oju ẹgbẹ jẹ jinna.

Ẹgbẹ ọdọ ni agbegbe Rẹmọ North ti ke si awọn agba oṣelu APC nijọba ibilẹ naa lati tun ero wọn yipada lori oludije fun ile igbimọ aṣofin wọn, nitori wọn ko fọwọ  si Onarebu Adebiyi Adelẹyẹ ti wọn mu.

Gẹgẹ bi ọrọ Ambasedọ Adewale Ibrahim, to jẹ alakoso ọdọ fun iṣejọba rere ati adari, ṣe wi nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe lorukọ ọdọ Rẹmọ Nọrth pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ ọdọ to n fẹ igbe aye rere fun orileede yii.

O sọ pe bigba ti wọn fẹẹ da omi iṣọkan ti wọn ti n mu nijọba ibilẹ naa ru ati pe niwọngba tawọn alatako oṣelu ko ba ko Wahala ba wọn, ko wa yẹ ki ẹgbẹ oṣelu APC ba ọjọ iwaju wọn jẹ lagbegbe naa.

Adewale fikun ọrọ ẹ pe gbogbo awọn ihuwasi Adelẹyẹ latẹyin ti mu wahala ba ẹgbẹ ọhun labẹle paapaa julọ iṣẹlẹ kan to waye nibi ti wọn ti yẹyẹ alaga meji ti wọn ti jẹ tẹlẹ nijọba ibilẹ naa, iyẹn Oloye Sofodu ati Oloye Adebanbọ.

O ni irun nnkan bẹẹ ti mu ki ẹgbẹ pin si yẹlẹyẹlẹ lati awọn igberiko, to si ti n ba nnkan jẹ.

Alakoso ọdọ ọhun wa ṣapejuwe Adebiyi gẹgẹ oṣiṣẹ awọn baṣejẹ, to ti da nnkan ru pupọ. O ni oun gan an lo n mu ifasẹyin ba ẹgbẹ APC agbegbe naa.

Bakan naa lo sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe bi wọn ṣe fun Adelẹyẹ ni tikẹẹti ẹgbẹ to ko jawe olubori ni agbegbe ibi to ti jade waa dibo,o ni ki ẹ fi le mọ pe awọn eeyan rẹ ko fẹran ẹ gan-an.

Ambasedọ ọhun tun sọ pe a fi ki wọn ko ẹgbẹ lẹ Adelẹyẹ lọwọ lo ṣe maa n ṣe lagbegbe, bi i pe ko jẹ oun nikan ni yoo maa dari ẹgbẹ atawọn oludije  eyi ti wọn lo n da wahala abẹnu silẹ.

Ọkunrin ọhun ni bi  wọn ko ba tete wa nnkan ṣe, gbogbo ohun Adelẹyẹ ṣe yii le mu ijakulẹ ba ẹgbẹ APC, ni Rẹmọ North ati ipinlẹ Ogun.

O waa rọ awọn adari APC  lapapọ lati feti si ọrọ awon ọdọ atawọn ọmọ ẹgbẹ lati le gba alaafia, ifẹ ati iṣọkan laaye.

No comments:

Post a Comment

Pages