Ẹ ma fojudi ẹgbẹ YPP Ogun ninu ibo ọdun to n bọ- Ọnarebu Adeyẹmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 24 May 2026

Ẹ ma fojudi ẹgbẹ YPP Ogun ninu ibo ọdun to n bọ- Ọnarebu Adeyẹmi

Ọnarebu Oluwaṣeyifunmi Adeyẹmi, alaga fẹgbẹ oṣelu Young Progressive Party, YPP, nipinlẹ Ogun ti paroko ranṣẹ pe awọn ti kọja ẹni ti wọn le fi ṣafojudi, nitori awọn ti mura silẹ fun ibo to n bọ lọdun 2027.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko ti wọn yan an pada sipo alaga ẹgbẹ naa atawọn oloye yooku,eyi to waye niluu Abẹokuta lọjọ Abamẹta, Satide.

O sọ pe gbogbo agbara lawọn yoo sa lati gbegba oroke nitori ẹgbẹ oṣelu tawọn araalu nifẹẹ si ni YPP.

Adeyẹmi ṣalaye pe o da oun loju pe YPP yoo di awọn ipo gidi mu,ti wọn ko si nii doju tawọn araalu.

O ni ẹgbẹ YPP jẹ eyi ti wọn da silẹ fun ootọ inu lati gbogun tiwa ibajẹ ati lati jẹ ki ara tu gbogbo ọmọ orileede yii.

Alaga YPP wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ki wọn wa nisọkan, alaafia ati ifẹ, bẹẹ ni wọn si ni aaye wa fawọn to ba fẹẹ darapọ mọ wọn, nitori ifẹ ijọba tiwa-n-tiwa jẹ wọn logun.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn aṣoju ajọ eleto idibo INEC, fun bi wọn ṣe waa ṣabojuto yiyan awọn oloye tuntun naa.

Ninu ọrọ Arabinrin Comfort Ọmọbọla Okenla, to jẹ olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ ọhun lo ti kọkọ dupẹ lọwọ awọn to wa nibẹ lọjọ naa, o bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ ọmọ ẹgbẹ lati le jọ ṣe aṣeyọri fun ijọba tiwa-n-tiwa yii.

Lara awọn oloye tuntun ti wọn tun yan lọjọ naa ni Ọgbẹni Damilare Okunlọwọ gẹgẹ bi akọwe atawọn yooku.

Bi ajọ eleto idibo INEC ṣe wa nibẹ bẹẹ lawọn agbofinro DSS atawọn oniroyin naa wa nibẹ

No comments:

Post a Comment

Pages