O ni bi ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ, bi wọn kọ awọn ni yoo gba Oke Mọsan lọwọ wọn ati pe eyi ti wọn ṣe naa ti to gẹ.
O sọrọ naa nibi yiyan awọn oloye tuntun fẹgbẹ ọhun lati wọọdu de ipinlẹ, eyi to waye ni ọfiisi ẹgbẹ wọn to wa ni Ijẹja, niluu Abẹokuta.
Alaga ọhun ti gboriyin fawọn ọmọ ẹgbẹ lori akitiyan lati le ri pe ẹgbẹ onipaki jẹ ọkọ igbala fawọn araalu lati wọ wọnu ọdun 2027.
O wa gba wọn lamọran lati rii pe wọn wa nisọkan, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba laarin wọn pẹlu afojusun lati rọwọ mu nibi ibo to n bọ naa.
Bẹẹ lo tun jẹ kawọn oloye ẹgbẹ tuntun mọ pe idagbasoke onipaki ọwọ wọn lo wa, o gba wọn lamọran lati fọwọsowọpọ laarin wọn,ki wọn si mu APM ni pataki.
Abayọmi sọ pẹlu igboya pe ẹgbẹ wọn nikan lo le wa ọna abayọ si Iṣoro to n de ba wa lorileede yii paapaa julọ ọrọ aje ati abo.
O ni awọn ti lawọn oludije to to gbangba sun lọyẹ ti wọn le koju APC, ti akoko ba to nibi ibo naa.
O waa rọ wọn lati ṣiṣẹ takuntakun fun APM Ogun, ki gbogbo wọn le jọ ṣaṣeyọri.
Ninu ọrọ oludije wọn fun ipo gomina,Rotimi Matthew Babajide, o ki awọn oloye naa ku oriire, o si fi wọn lọkanbalẹ pe awọn ni yoo jawe olubori lọdun 2027.
No comments:
Post a Comment