Gẹgẹ bi atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ ẹ, to tun jẹ oluranlọwọ nipa iroyin fun ṣẹnetọ ọhun iyẹn Oloye Kayọde Ọdunaro fi sita lonii, lo ti ṣalaye pe pẹlu ayọ kikun ni oludije naa fi n dupẹ oore nla ti wọn ṣe fun un yii.
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun agbegbe Ogun West nile igbimọ aṣofin apapọ niluu Abuja, ṣapejuwe ipade ti wọn ṣe ti wọn fi fa ọwọ ẹ soke gẹgẹ isọkan ati ifẹ ti wọn fi yanju gbogbo ẹ.
O mọ ọn mọ dupẹ ni pataki julọ lọwọ Aarẹ Tinubu ati iyawo ẹ fun ifarajin wọn lati le jẹ ki Ogun West fa gomina kalẹ fun igba akọkọ ninu itan ipinlẹ Ogun lati bii aadọta ọdun ti wọn ti da a silẹ.
Bẹẹ ni ko gbagbe Gomina Dapọ Abiọdun ati iyawo ẹ fun igbagbọ to ni ninu oun atawọn atilẹyin to ti n ṣe foun latigba to ti kuro nipinlẹ Eko, wa si Ogun.
Bakan naa lo mẹnuba awọn ipa ti Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba ati alaga ẹgbẹ wọn, Oloye Yẹmi Sanusi ko lakooko ti igbesẹ naa n lọ lọwọ, ti wọn duro bii baba ati ma jẹ ko bajẹ.
O waa dupẹ pata lọwọ gbogbo awọn ti wọn jọ dije, ti wọn juwọ silẹ foun, fun agbọye ati ifarajin wọn fun ẹgbẹ oṣelu APC, o ni ko sẹni to jakulẹ ninu gbogbo nitori mọlẹbi kan naa ni wọn.
Sẹnetọ Adeọla waa lo anfaani naa lati bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ ati atilẹyin to gbooro lọwọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ajọ pẹlu gbogbo araalu lati le mu oun ṣe aṣeyọri nipa ki erongba ẹ lati di gomina le waa ni imuṣẹ, bẹẹ lo ṣeleri pe oun ko ni figba kankan ba wọn loju jẹ.
No comments:
Post a Comment