Mo faramọ igbesẹ ẹgbẹ wa APC lori oludije ipo gomina- Tunde Lẹmọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 15 April 2026

Mo faramọ igbesẹ ẹgbẹ wa APC lori oludije ipo gomina- Tunde Lẹmọ

Tunde Lẹmọ, igbakeji ọga agba banki ilẹ wa tẹlẹ, to tun dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti sọ pe oun faramọ igbesẹ ti wọn gbe lori bi wọn ṣe mu Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo gomina lọdun 2027.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ẹgbẹ lagbara nnkan ti wọn ba si fẹẹ dandan ni lati bawọn fẹ fun isọkan, ifẹ ati alaafia.

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lonii, lo ti sọ igbesẹ naa jẹ eyi to lagbara ju, to si dara pupọ.

O sọ pe o san ju ki wọn ni ki wọn lọọ fiṣẹ ijọba ti wọn ṣe silẹ.O ni oun nigbagbọ ninu Sẹnetọ Yayi ti wọn fa kalẹ, nitori o kaju ẹ.

Tunde Lẹmọ tun fikun ọrọ ẹ pe gbogbo awọn agba ẹgbẹ ni wọn gbagbe Yayi le ṣe e nitori awọn aṣeyọri to ti ni ati pe yoo tun le tẹsiwaju iṣẹ rere ti ẹni to n ṣejọba lọ ti ṣe.

Bẹẹ lo sọ pe erongba fifa ọmọ oye kalẹ yii yoo tun tan ka gbogbo awọn igun mẹtẹẹta nipinlẹ Ogun pẹlu isọkan 

O ṣalaye pe awọn wahala abẹnu ti fẹẹ maa mu ipinya wa tẹlẹ to si fẹẹ maa dena ilọsiwaju ẹgbẹ ṣugbọn o ni o yẹ ki wọn tete yanju ẹ ki idibo to waye.

 O waa rọ gbogbo awọn oloolufẹ ẹ kaakiri ipinlẹ Ogun lati bẹrẹ atilẹyin fun Sẹnetọ Adeọla lakooko ipolongo ki wọn ma ṣe boju wẹyin.

O tun waa dupẹ lọwọ gbogbo awọn adari ẹgbẹ APC nipinlẹ ati lapaapọ fun igbagbọ ati atilẹyin wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages