Idanilẹkọọ ọhun lo waye pẹlu ajọṣepọ ileeṣe ofin kan ti wọn pe ni FOlegal Law firm, eyi to waye ni ọfiisi ẹgbẹ wọn niluu apapọ.
Awọn alaga ẹgbẹ kọọkan ti wọn jẹ IPAC,ni wọn wa nibẹ lati tun ni ẹkọ si nipa idibo to n bọ lọna naa.
Agbẹjọro Festus Ogun lo ṣaaju awọn yooku ẹ wa nibi ti wọn ti sọ pataki ohun tawon ofin eto idibo naa rọ mọ ati ojuṣe ẹgbẹ oṣelu kọọkan ki wọn ma ba a ko wọn mọ ẹrẹ.
Bẹẹ lo mẹnuba anfaani ati akoba to rọ mọ ṣiṣe eto idibo lorileede yii. O tun ṣekilọ fun wọn lati sọra fawọn nnkan to le da wahala silẹ, ni eyi to lodi sijọba tiwa-n-tiwa.
Agbẹjọro yii tun lawọn lọyẹ lori bi wọn ṣe le yan oludije lọna ti ofin la kalẹ ati bi wọn ṣe le yọ, to ba jẹ pe onitọhun ko koju oṣuwọn to.
Bẹẹ ni wọn tun sọ fun wọn ọna ti wọn le gba lakooko ti ibo ba n lọ lọwọ,ati bi wọn ba fẹẹ ka ibo atawọn ojuṣe wọn.
Lẹyin idanilẹkọọ ọhun lawọn ọmọ ẹgbẹ beere oriṣiriṣi ibeere, ti wọn si da wọn lohun.
Ninu ọrọ alaga IPAC nipinlẹ Ogun, Abayọmi Sanyaolu, o dupẹ lọwọ awọn ti wọn wa ṣe idanilẹkọọ naa fun wọn, o sọ pe awọn lo ri awọn ẹkọ nla di mu nibẹ.
O ṣapejuwe idanilẹkọọ naa gẹgẹ atupa to jẹ kawọn tubọ mọ si nipa bo ṣe n lọ si nidii oṣelu.
O wa mu dawọn ọmọ ẹgbẹ loju pe loorekoore ni iru idanilẹkọọ bẹẹ yoo maa waye.
Nipari ohun gbogbo wọn fun gbogbo awọn to kopa nibi idanilẹkọọ ọhun ni iwe ẹri.
No comments:
Post a Comment