Tinubu, Ọbasanjọ, Ọṣọba rọjo adura le Abiọdun lori fun papakọ ofurufu tuntun ti wọn ṣi. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 5 April 2026

Tinubu, Ọbasanjọ, Ọṣọba rọjo adura le Abiọdun lori fun papakọ ofurufu tuntun ti wọn ṣi.

Pẹlu tinutinu tọkantọkan ni Aarẹ orileede yii Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba atawọn mii ti wọn sọrọ fi rọjo adura le Gomina Dapọ Abiọdun lori fawọn aṣeyọri nla to ti ṣe, eyi to ti mu ipinlẹ naa goke.

Nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu tuntun iyẹn Gateway Airport to wa ni Iliṣan to waye lọjọ Abamẹta, Satide, lawọn agba oṣelu yii ti gboriyin, ti wọn ṣi sadura fun lakooko ti wọn sọrọ.

Ninu ọrọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lo ti fi idunnu ẹ to si sọ pe awọn ko kabamọ rara fawọn nnkan tawọn ba ṣe fun Dapọ Abọdun, nitori o huwa ẹ, o si ṣiṣẹ ẹ pẹlu.

Aṣiwaju tun sọ pe"Laaarin ọdun meje, iwọ Dapo Abiodun ti ṣafihan ifarajin, afojusun ati akikanju lati mu Naijiria dagba soke, a ba ọ yọ lori idagbasoke apapọ yii.

O ni tọkan tọkan loun fi dupẹ fun nnkan to  ri yii O niajọyọ afojusun to ni ipa rere ti gomina ati awọn gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun lawọn ṣe.

Tinubu ni ".A n ṣe ifilọlẹ agbegbe eto ọrọ aje tuntun to wa ni arọwọto wa, mi o si kabamọ lori ohunkohun ti a ti ṣe pẹlu yin,  gẹgẹ bi aarẹ yin, inu mi dun lati rii pe ẹ lo owo ijọba apapọ ti a gbe soke fun un yin daradara lati mu ki orileede wa tẹsiwaju

Tinubu sọ pe papakọ ofurufu naa ṣafihan pe Gomina Abiodun lo awọn owo to n gba daradara.

Ninu ọrọ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi idunnu ẹ lori papakọ ofurufu ti wọn ṣi naa,iwuri nla lo pe e.

O fi ẹmi imoore ẹ han si Gomina Abiodun fun bo ṣe kọ papakọ ofurufu naa lati ibẹrẹ titi de opin.

O ni "Mo ti wọ ọkọ ofurufu lati Abuja wa si Iliṣan, o si gba mi ni iṣẹju marundinlaadọta lati de ile mi, eleyi lo si jẹ iṣẹju marundinlọgbọn, lo fi dinku ti mo maa fi n rin ka ni Eko ni mo gba wọle.

Nigba ti Gomina Abiodun sọrọ, o fi dunnu rẹ han si aarẹ fun atilẹyin lati jẹ ki erongba naa waye nipa afikun owo tijọba apapọ n fun awọn ipinlẹ.

O sọ pe agbekalẹ Aarẹ Tinubu lori atunṣe Ireti ti jẹ ki Naijiria wa ni ipo rẹ fun agbegbe lati dokoowo si fun awọn olokoowo agbaye.

Abiodun sọ pe nigba toun gba ijọba lọdun meje sẹyin, oun pinnu lati di alafo to wa laaarin ipinlẹ Ogun ati Eko, to si lo jẹ ohun iwuri pe ala rere oun wa si imuṣẹ.

O wa jẹ ko di mimọ pe ọkan pataki ni ipinlẹ Ogun jẹ ninu awọn ipinlẹ ti eto ọrọ aje rẹ tete n ni idagbasoke nilẹ Naijiria, nipa awọn agbekalẹ ati ilana.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe yatọ si papakọ ofurufu tuntun yii, ati ọkọ baluu tuntun meji ti ijọba ipinlẹ naa ni, iṣakoso oun tun ti ṣe ọpọlọpọ opopona to le diẹ ni ẹgbẹrun kan aabọ kilomita ati ile gbigbe olowo pọọku ti ko din ni ẹgbẹrun meje.





No comments:

Post a Comment

Pages