Awọn ọmọlẹyin Tunde Lẹmọ ṣe bẹbẹ lọjọ ti Tinubu wa ṣi papakọ ofurufu ni Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 5 April 2026

Awọn ọmọlẹyin Tunde Lẹmọ ṣe bẹbẹ lọjọ ti Tinubu wa ṣi papakọ ofurufu ni Ogun.

Lati le fi ifẹ ti Tunde Lẹmọ, igbakeji ọga agba fun ileeṣẹ banki ilẹ wa tlẹ ni si Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, lo mu kawọn alatilẹyin ẹ tu jade lati waa pade aarẹ nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu tuntun to wa ni Iliṣan ipinlẹ Ogun.

Lati nnkan bii aago mẹjọ aarọ lawọn alatilẹyin Tunde Lẹmọ, to tun dije fun ipo gomina nipinlẹ naa ti n tu jade waa sibi ayẹyẹ ọhun.

Pẹlu oriṣi patako ti aworan Aarẹ Tinubu pẹlu Tunde Lẹmọ wa ni wọn gbe kaakiri ti wọn si fi aarẹ ati Tunde Lẹmọ kaabọ sibi ayẹyẹ ọhun.

Tunde Lẹmọ toun naa wa nibẹ lọjọ naa lawọn alatilẹyin ẹ kọkọ lọọ filu ati ijo pade ẹ.

Ninu ọrọ Tunde Lẹmọ lo ti sọ pe ohun iwuri nla lo waye lọjọ naa to si gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ku oriire papakọ ofurufu yii.

O ni ọkan lara nnkan ti yoo mu ki ọrọ aje sun soke, ti yoo si tun pese iṣẹ fawọn araalu.

Bi o ṣe n ki Aarẹ Tinubu kaabọ pe o wa ṣi papakọ ofurufu yii bẹẹ naa lo tun ki Gomina Dapọ Abiọdun ku oriite aṣeyọri nla to ṣe yii.

No comments:

Post a Comment

Pages