Ọga aṣọbode ṣabẹwo si Olu Ilaro atawọn ọba kan nilẹ Yewa lati dena kiko ohun ija oloro wọlu lakooko idibo to n bọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 22 April 2026

Ọga aṣọbode ṣabẹwo si Olu Ilaro atawọn ọba kan nilẹ Yewa lati dena kiko ohun ija oloro wọlu lakooko idibo to n bọ

Pẹlu bi eto idibo ṣe n sunmọle gbogbo ọna nileeṣe aṣọbode ipinlẹ Ogun n wa lati rii pe eto aabo to peye wa lati ma jẹ ki wọn ko ohun ija ogun wọlu.

Idi nyii ti ọga agba wọn nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Afẹni ṣe ṣabẹwo lọ sọdo Olu tiluu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle atawọn ọba ilẹ Yewa kan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni abẹwo ọhun ṣe pataki lati fi le jọ jiroro lori ọna ti wọn le gba lori eto aabo lẹnu ọna aala ilẹ wa.

O sọ pe ilẹ Yewa lapapọ jẹ ibi pataki ti wọn mule tawọn to wa lorileede mii in ti wọn jọ paala pọ. O ni ko wa yẹ ki wọn sọ ọ di ibi ti wọn yoo ti ba eto ijọba dẹmọkireesi ta a n ṣe jẹ.

Afẹni tun fikun ọrọ ẹ pe awọn wa lati wa gba ire latọdọ awọn ọba alaye ati bi ifọwọsowọpọ yoo ṣe laarin wọn atawṣn eeyan agbegbe ilú .

O tun wa sọ nipa awọn igbesẹ ti wọn ti gbe sẹyin lati le jẹ ki ikansiraẹni maa waye laarin atawọn to n gbe ni ẹnu ala,ki abo ba tun le gbooro si.

Bẹẹ lo ni awọn aṣọbode ipinlẹ Ogun ko kaarẹ lati gbogun tawọn onifayawọ, nitori ẹ lawọn ko ṣe fi wọn lọkanbalẹ.

Ninu ọrọ Ọba Kẹhinde Olugbenle, o gboriyin fawọn akitiyan tawọn aṣọbode n ko lawujọ lori igbogun tawọn onifayawọ ti wọn ba ọrọ aje orileede yii jẹ.

Bẹẹ lo tun mẹnuba akitiyan awọn ọmọ Yewa lapapọ lori bi wọn ṣe n gba alaafia laye,  O ni ko si nnkan to dara ju ki alaafia jọba lọ.

O waa sọ pe awọn yoo tẹsiwaju nipa ilanilọyẹ awọn ọdọ lori bi wọn ṣe le jawọ nidii iṣẹ fayawọ,lati jẹ ki wọn mọ pe owo ti ko pe e ni.

Bakan naa ni ọga awọn aṣọbode yii tun ṣabewo de ọdọ Onihunbẹ ti Ihunbẹ, Olu tiluu Owode ati Obelle.


No comments:

Post a Comment

Pages