Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni kutukutu owurọ yii ni wọn ṣadeede ri awọn ọlọpaa pẹlu mọtọ akọta mi, ti wọn si n yẹ awọn to kọja wo.
Iwadii fi ye wa idi pataki ti wọn fi ko ọlọpaa lọọ sibẹ ni lati ma jẹ kawọn eeyan wọle sibi iwọde ti Sẹnetọ Gbenga Daniel maa n ṣe, eyi to fi sọri BATOGD iyẹn Bọla Ahmed Tinubu ati Otunba Gbenga Daniel.
Nibi iwọde ọhun ni wọn ti maa n ṣagbeyẹwo awọn iṣẹ ti Sẹnetọ Gbenga Daniel ti ṣe gẹgẹ aṣoju wọn iyẹn Ogun East nile igbimọ aṣofin apapọ niluu Abuja.
Eyi ti wọn sọ pe o ti ṣe kaakiri awọn ijọba ibilẹ to wa ni abẹ Ogun East, ṣugbọn ti wọn fẹẹ ṣe ti Ijẹbu Ode, ko to do pe awọn ọlọpaa lọ ti ibi ti wọn fẹẹ lo pa.
Ọpọ awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn sọ pe ọrọ naa lọwọ oṣelu ninu ati pe wọn fẹẹ maa lo ipo agbara le ara wọn lori.
Bi ẹ o ba gbagbe ija oṣelu yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ laarin Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun ati Sẹnetọ Ọtunba Gbenga Daniel.
Eyi lo faa nigba kan tawọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun fi kede nigba kan pe awọb ti le Gbenga Daniel ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn ti igbesẹ naa forisanpọn titi di akoko yii.
Ni ọjọ Aje, Monde, ijẹta yii ni wọn tun foṣelu han Sẹnetọ Gbenga Daniel nigba ti wọn ko jẹ ko wọle sibi ipade awọn alẹnulọrọ Ogun East, nibi ti wọn ti kede Dapọ Abiọdun, bii oludije fun ipo sẹnetp ni ẹkun naa.
Wahala to wa nilẹ yii ti ko tii tan ni wọn sọ pe wọn tun fi agbara lati ma jẹ ki Gbenga Daniel ṣe iwọde, eyi to ti bẹrẹ lati ọdun to kọja.
No comments:
Post a Comment