Ọdun ajinde wa fun isọkan, ifẹ ati alaafia Tunde Lẹmọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 4 April 2026

Ọdun ajinde wa fun isọkan, ifẹ ati alaafia Tunde Lẹmọ

Tunde Lẹmọ, igbakeji ọga agba banki ilẹ wa tẹlẹ, ti gba awọn Kristẹẹni lorileede yii nimọran ki wọn fi akoko ọdun ajinde to n lọ lọwọ yii lati fi mu ireti, isọdọtun ati ifira ẹni silẹ lati fi da ogo pada paapaa nipinlẹ Ogun.

Ninu atẹjade to fi sita lati fi ki gbogbo wọn ku ayẹyẹ ajinde, o sọ pe ọdun to n lọ lọwọ naa kọja nipa ẹsin bi ko ṣe iranti fun agbara to wa fun itusilẹ, ayọ ninu ireti ati iforiti.

Tunde Lẹmọ, ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina ṣalaye siwaju pe bi Aarẹ Tinubu ṣe fi ara rẹ silẹ lati sinlu ti mu aṣeyọri nla ba eto isakoso ẹ, paapaa julọ
 idagbasoke rere to ti mu ba ọrọ aje.

O waa gbogbo awọn ọmọ orileede yii ki wọn fi ayẹyẹ ọdun ajinde naa wa isọkan, ifẹ ati alaafia jọba laaarin wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages