Pẹlu orin ọlọkan-ọj-ọkan ni wọn fi ki i kaabọ saarin wọn,toun naa ko si fi para, toun naa ki ijo mọlẹ.
Lara awọn agba oṣelu ti wọn wa nibẹ ni Ọnarebu Ọmọtayọ Rotimi, Ọnarebu Jubril Olanṣile Odulatẹ, to ṣoju Ọnarebu Salami Isiaka ati Ọnarebu Olukọya Adedoyin atawọn mii in.
Ninu ọrọ ẹ, Sẹnetọ Ọbasanjọ dupẹ lọwọ awọn eeyan ọhun fun ifẹ ti wọn ni si oun lati gba a lalejo.
Bẹẹ lo tun ṣalaye idi to fi fẹẹ dupo gomina, o ni bo tilẹ jẹ pe akoko ibo ko tii bẹrẹ amọ oun ni lati waa fi to wọn leti gẹgẹ bi erongba ẹ lati jade dupo
O waa bẹbẹ fun atilẹyin awọn eeyan ọhn lati le jẹ ko ri tikẹẹti naa gba.
Ninu ọrọ agba ẹgbẹ ti wọn sọ nibẹ ni wọn ti gboriyin fun un fawọn ipa ribiribi to ti ko sẹyin, eyi to ni wọn ṣi fọhun sibẹ.
Wọn wa mu daa loju pe gbọingbọin lawọn wa pẹlu ẹ.
No comments:
Post a Comment