Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Aṣofin ọhun lọọ gba fọọmu yii ni miliọnu lọna aadọta niluu Abuja.
Bi si ṣe gba a tan lo ti gbe sori ẹrọ ayelujara pẹlu aworan nibi to ti ko fọọmu ọhun dani, to si n sọ fawọn ọmọlẹyin ẹ pe ki wọn fọkanbalẹ.
Ninu ọrọ ẹ to sọ sibẹ lo ti sọ pe, "Mo ti gba fọọmu gẹgẹ bi oludije fun ipo sẹnetọ lẹẹkeji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Mo ṣe eleyii lati fi le tẹsiwaju erongba lati fi pese awọn nnkan tawọn eeyan mi n fẹ ni agbegbe Ogun East fun idibo ọdun 2027".
Iwadii fi ye wa pe bawọn kan ṣe gbọ nipa igbese ti ẹni to ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ Ogun gbe ni girigiri ti n de bawọn.
Idi abajọ ni ti wahala to waye lọsẹ to kọja niluu Ijẹbu Ode, nibi ipade alẹnulọrọ awọn agba oṣelu APC ti Ogun East, ti wọn ko jẹ ki Daniel atawọn eeyan wọle si gbọngan ti wọn ti ṣe.
Ibi ipade ọhun ni wọn ti mu Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo sẹnetọ amọ ti ko dun mọ awọn alatilẹyin Daniel ni inu.
Ṣugbọn wọn ni wọn ko mọ ibi ti Daniel atawọn ọmọ ẹyin ẹ fẹẹ gba yọ si wọn pẹlu ohun ti wọn ṣe fun wọn yii.
Idi niyii ti wọn fi ni aifọkanbalẹ deba wọn nigba wọn gbọ Sẹnetọ Daniel ti pada gba fọọmu gẹgẹ bi oludije ni Ogun East.
No comments:
Post a Comment