Nibi eto ori redio Eagle 102.5 FM, ni ọkunrin naa ti sọrọ yii lakooko to n kopa, o sọ pe gbogbo isokusọ tawọn kan sọ pe ija alagbara igun ni wọn n ba ara wọn ja, to si si ni wọn kan fẹẹ fi da ogun abẹle silẹ
Nuberu ṣalaye pe ko si igun kankan bawọn eeyan ṣe n gbe kaakiri fawọn araalu ati pe ibẹ gan an wọn ti n ṣi awọn lọkan.
O sọ pe, "Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe titi di akoko yii, ọkan naa ni APC, nipinlẹ Ogun ati pe ilana ẹgbẹ ọhun ko yipada lati wọọdu titi de ipinlẹ pẹlu awọn aṣaaju ta a da mọ".
O ṣalaye siwaju pe awọn ko ni alaga meji ni APC, Ogun East, bẹẹ lawọn ko ni olori ọdọ meji, ko si sẹni to n da tiẹ ṣe nibẹ.
Nubwru ni "Ohun ta a ni ni ẹgbẹ kan, ilana kan ati adari kan tawọn adari yẹn ba si ti sọrọ, lori isọkan ni gbogbo ẹ dale lori, gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo tii gba wọle.
Nipa iṣẹlẹ kan to waye nibi ipade alẹnulọrọ awọn agba ẹgbẹ naa ti Ogun East nibi ti wọn ti mu oludije sẹnetọ ti wọn ko jẹ Sẹnetọ Gbenga Daniel wọle, Nuberu sọ pe ki i ṣe bọrọ naa ṣe jẹ ni wọn n sọ ati pe asọdun lasan ni.
O ṣalaye pe ẹni to ba jẹ adajọ gidi ko nii maa gbọ ẹjọ ẹnikan da ati pe owe Yoruba sọ pe a gbọ ẹjọ ẹnikan da agba oṣika ni.
Nuberu ni nnkan tawọn si maa n ṣe ninu ẹgbẹ wọn niyii, nitori awọn maa n fẹ wadii okodoro.
O sọ pe titi di akoko yii ko sẹni to wa fẹjọ sun pe wọn ko jẹ kawọn kopa gẹgẹ bi ẹtọ wọn nibi ipade naa, nigba ti iru nnkan bẹẹ ko ti waye ko si nnkan tawọn fẹẹ ṣe.
O wa pe akiyesi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pe bi ikunsinu ba tiẹ wa, ohun to ṣe pataki ni lati mu wa sinu ẹgbẹ ki wọn si yanju ẹ ni itunbi inu bi.
Lori ọrọ pe wọn ti le awọn kan ninu ẹgbẹ,alukoro APC Ogun sọ pe ẹgbẹ lapapọ ti da si ọrọ naa ti wọn si sọ pe ki gbogbo ṣi wa bo ṣe wa, nitori idi eyi, ko sẹni ti wọn si le.
O gba awọn araalu paapaa ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun nimọran lati ma ṣe tẹti si ọrọ wọn ni wọn pe tabi ahesọ nitori gbogbo eleyii wahala lo maa n da silẹ.
No comments:
Post a Comment