O fẹẹ jẹ pe ko si oloṣelu ọmọ ẹgbẹ APC,ti ko si nibẹ lọjọ bẹẹ lo jẹ pe ṣe lawọn oludije fun ibo to n bọ fi ibẹ ṣe pagede.
Ọkan lara awọn oludije ọhun ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, to n dije fun ipo gomina lọdun 2027,labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọrọ tẹnu kọ kekere kọ lawọn alatilẹyin ẹ to wa nibẹ lati ṣatilẹyin fun obinrin naa. Iwadii fi ye wa o fẹẹ jẹ pe kaakiri ipinlẹ Ogun lawọn to n ṣe ti ẹni to da ajọ Iyaniwura ti wa
Bi awọn kan ṣe wọ aṣọ kampala ẹgbẹjọda ti wọn kọ Ko sọmọ bii Iyabọ, bẹẹ lawọn kan wọ ṣokoto pẹlu ẹwu ṣaati, ti wọn ya aworan pẹlu fila.
Iyẹn nikan kọ oriṣi patako ti wọn ya aworan Iyabọ Ọbasanjọ pẹlu Tinubu ati Dapọ Abiọdun ni wọn n gbe kiri.
Nibi ti wọn nifẹẹ obinrin naa de ẹsẹ lọpọ fi rin lati ẹnu bode debi ti ayẹyẹ ọhun ti waye, ti wọn si kọrin oriṣi lati fi ṣapọnle oludije wọn yii.
Ninu ọrọ Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ lo ti gboriyin fun Aarẹ Tinubu fawọn eto to n ṣe lati le ṣatunṣe si ọrọ aje wa.
Bẹẹ lo ṣapejuwe papakọ ofurufu ọhun gẹgẹ bi idagbasoke ti yoo tun idẹrun bawọn to ba n rim irinajo.
Bakan lo tun gboṣuba o kare fun Gomina ipinlẹ Ogun,Ọmọọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to n lo ọgbọn ati oye ti Ọlọrun fun lati mu idagbasoke ati idẹrun bawọn araalu
No comments:
Post a Comment