Ẹ ma fọtẹ ba oun to dara jẹ GNI leeyan wa latilẹ lorin tawọn alatilẹyin GNI n kọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu to waye l'Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 5 April 2026

Ẹ ma fọtẹ ba oun to dara jẹ GNI leeyan wa latilẹ lorin tawọn alatilẹyin GNI n kọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu to waye l'Ogun.


Bi wọn ba sọ nipa awọn alatilẹyin to lero julọ nibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu ti Aarẹ Bọla Ahmed wa ṣi lọjọ Abamẹta to kọja yii, Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn /Yewa North, nile igbimọ aṣoju ṣofin niluu Abuja.

Ọlọrun nikan lo le sọ bawọn alatilẹyin ọhun ṣe pọ to lati wa yẹ GNI, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC,nipinlẹ Ogun, nibi ayẹyẹ to waye ọhun.

Aṣọ ẹgbẹjọda tiaworan GNI wa ni wọn wọ pẹlu patako ti wọn gbe soke lati fi polongo oludije wọn yii.

Bẹẹ ni orin ọlọkam-ọ-jọkan waye lati fi ṣayẹso ẹ lọjọ nsa koda ki Ọnarebu Gboyega Isiaka to debẹ lawọn eeyan ẹ yii ti de, ti wọn ko si jẹ ko rẹ wọn.

Lara orin ti wọn kọ lọjọ naa ni pe ki wọn maa fi ọtẹ ba nnkan to dara,ọmọ wa GNI latilẹ.atawọn orin oṣelu loriṣiriṣi lati fi polongo oludije wọn.

Ninu ọrọ ỌnarebuGboyega Nasir Isiaka  lo tì sọ pe inu oun pe oun darapọ mọ Gomina Dapọ Abiọdun ki Aarẹ Tinubu kaabọ sibi ayẹyẹ ṣiṣi papakọ ofurufu to wa ni Ipẹru.

O sọ pe ayẹyẹ to waye ọhun jẹ itan ayeraye to ṣapejuwe irinajo idagbasoke ipinlẹ Ogun latọdọ Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi erongba ẹ si rere.

O ṣapejuwe Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi adari rere ati iwoye ọjọ iwaju ẹ lo bi papakọ ofurufu ti wọn ṣẹṣẹ ṣi naa.

O waa ni ifarajin Gomina lo bi ọpọ aṣeyọri to mu ba ipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages