O sọrọ yii lakooko ti Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣabẹwo si ẹgbẹ awọn apapọ oṣelu, IPAC, tipinlẹ Ogun, nibi to ti lọọ fi erongba ẹ han gẹgẹ bi oludije gomina.
O sọ pe awọn oludije mẹta tawọn ṣi mọ ni Senetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla ati Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka.
O ni awọn mẹta yii ni wọn ko fọrọ awọn IPAC sẹyin, ti wọn si ti wa lati bawọn sọ erongba wọn lati dije fun ipo gomina.
Alaga fẹgbẹ IPAC tun ṣalaye siwaju pe gbogbo apapọ ẹgbẹ oṣelu lawọn jọ wa ati pe ẹnikẹni to ba fẹẹ dije ni lati wa sọdọ wọn lati wa sọ nnkan to baa ni fun araalu.
O ṣalaye siwaju pe" Oludije to ba fẹẹ jade dupo ninu ẹgbẹ kọọkan gbọdọ wa si ọfiisi ijọba tiwa-n-tiwa yii lati gbe nnkan to ba ni sita ka jọ ọ gbe yẹwo.
Abayọmi sọ pe awọn ko nii ṣatilẹyin fun ẹnikẹni ti ko ba le ṣagbekalẹ eto iṣejọba rere fawọn araalu.
O sọ pe to ba to akoko awọn yoo pe gbogbo awọn oludije kọọkan lati jọ jokoo papọ lati ṣagbeyẹwọ erongba wọn fawọn araalu.
Bẹẹ lo gboriyin fun Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ fun bi o ṣe ṣapọnle wọn lati wa ṣepade pọ pẹlu wọn nigba erongba ẹ lati di gomina .
O ṣapejuwe obinrin ọhun gẹgẹ bi akikanju to ni ẹmi igboya lati le koju awọn ọkunrin ti wọn jọ figagbaga fun idije gomina naa.
Ko to akoko yii ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ti kọkọ ki awọn oloye ẹgbẹ IPAC ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan wọle ku oriipe pẹlu adura pe asiko wọn yoo rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lọrun.
O ni bi wọn ṣe fọwọsowọpọ dibo oloye tuntun laisi wahala kankan jẹ ohun iwuri nla.
No comments:
Post a Comment