Ninu atẹjade to fi sita lo ti ba gbogbo awọn Kristẹẹni yọ fun ipari awẹ,ati ọdun Jimọ rere pẹlu ajinde to n bọ lọna.
O kọkọ bawọn dupẹ pe ẹmi wọn to bẹrẹ awẹ ọhun lo pari ẹ layọ ati alaafia nitori ki i ṣe nnkan to rọrun rara.
Filani tun sọ ninu ọrọ ẹ pe akoko ta a wa yii ki i ṣe fun idakẹrọrọ bi ko ṣe lati tun fi adura ran awọn to n dari wa lọwọ ki Ọlọrun- ko si wọn ninu lati mu wa de ebute rere.
Ọkunrin naa tun fi aidunnu ẹ han lori igbesẹ to nijọba apapọ n gbe lori ẹyawo biliọnu mẹfa owo ilẹ okeere
O ni kii ṣe iru akoko yii ti orileede wa n foju winna ọna ti ipawowọle lori ọrọ epo yoo tun ṣe gberu si.
Filani tun ṣalaye siwaju pe"Igbesẹ to buru jai nijọba apapọ fẹẹ gbe lakooko yii lori ẹyawọ biliọnu mẹfa owo ilẹ oke okun nibi to jẹ pe a ṣi n wa ọna ti ipawowọle lori ọrọ epo yoo ṣe gberu sii.
"Pẹlu bi wọn ṣe n ta epo ti n kọja eto iṣuna, to yẹ kawọn ọmọ orileede yii maa nipa rere ninu eto ọrọ aje, ko yẹ ki wọn tun maa di ẹru wiwo le wọn lori.
O sọ pe nnkan to yẹ ki ijọba apapọ maa ṣe faraalu lakooko yii ni bi wọn yoo ṣe gunle awọn ohun idagbasoke imayedẹrun, eyi ti ko nii ṣakoba fun ọrọ aje, ki i ṣe pe ki wọn tun ko wa sinu oko gbese.
Filani waa sọ pe bi a ṣe ṣayẹyẹ ọdun ajinde, o yẹ ki a ṣe isọdọtun ireti to le mu aṣeyọri wa.Ki a si fi isọdọtun yii tun opo orileede wa gbe dide.
Gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu YPP ,o ni oun ṣi lori ero oun lati ṣejọba lọna ti yoo mu idẹrun ba araalu, ti idagbasoke yoo si fi wa kaakiri.
No comments:
Post a Comment