O fẹẹ jẹ pe ko si iru ipade isọkan bẹẹ ri laarin awọn agba oloṣelu to wa ni Ogun West, nibi ti wọn ti jọ jiroro atilẹyin lori bi Yayi yoo ṣe wọle fun ipo naa ti Yewa yoo si jẹ gomina fun igba akọkọ.
Ohun to tun jẹ ki ipade naa tun jẹ kayeefi ni bi awọn ti wọn jọ dije fun ipo gomina ni ẹkun ọhun ṣe wa nibẹ ti wọn si sọrọ iwuri atilẹyin wọn.
Awọn to wa nibẹ ni Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, Ọnarebu Biọdun Akinlade,Igbakeji Gomina nipinlẹ Ogun, Onimọ ẹrọ Nọimọt Oyedele Salakọ, Dokita Isiaq Salakọ, minisita feto ilera,Ọnarebu Tunji Akinosi, Sẹnetọ Akin Ọdunsi, Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo atawọn agba oṣelu mii in.
Ninu ọrọ to n fi ki wọn kaabọ, Dokita Salakọ kọkọ fi idunnu ẹ han lori bi ẹsẹ ṣe pe nibi ipade ọhun, o waa mu wa si iranti pe lati ọdun 1976, ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, ẹdun ọkan lo jẹ pe awọn ko tii ni gomina kankan lati ọdọ wọn wa. Ọpọ ipa lo ni awọn ti sa to jẹ pe pabo ni.
O tun ṣalaye siwaju pe" Ọpọ ipa lati sa lati jẹ ki gbogbo wa ni Ogun West pa ẹnu pọ nisọkan lati ni gomina ṣugbọn pabo lo ja si. Ṣugbọn bi wọn ṣe mu Sẹnetọ Yayi bi oludije, gbogbo wa ni lati pa ẹnu pọ.Ohun ti ipade wa da lori ni ọna lfarajin ki Yayi le di gomina fun igba akọkọ.
Bakan naa alaga fẹgbẹ oṣelu APC Ogun West, Azeez Ekwueme, fi idunnu ẹ han lori mimu ti wọn mu Yayi, o ni eyi fi apẹẹrẹ rere lelẹ ati iṣọkan.
O sọ pe "Pẹlu agbekalẹ yi yan oludije yii o fihan pe inu gbogbo awọn eeyan lo dun si ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun.Mo wa ro gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati wa nisọkan atilẹyin fun oludije wa"
Ninu ọrọ ti Ọnarebu Adekunle Akinlade, toun naa dije fun ipo gomina ko to juwọ silẹ, lo ti rọ gbogbo ọmọ Ogun West, ki wọn parapọ lati ṣiṣẹ fun Yayi ninu ibo ọdun to n bọ.
Ọnarebu Gboyega Isiaka sọ ni tiẹ pe akoko ta a wa yii ti kọja ki a maa ṣe ẹtanu oṣelu bi ko ṣe ki gbogbo wọn jọ parapọ fimọsọkan ṣiṣẹ fun oludije wọn lati Ogun West, ki nnkan ti wọn fẹ le tẹ wọn lọwọ.
Ṣugbọn Ọnarebu Biọdun Akinlade ṣapejuwe Ilana ti APC tọ lati mu oludije wọn gẹgẹ bi ohun itan manigbagbe ninu itan ipinlẹ Ogun fun idagbasoke.
O ni pẹlu gbogbo nnkan to wu to ti lẹ ṣẹlẹ eeyan ẹlẹran ara ni oun, GNI ati Yayi. Bẹẹ lo gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun fawọn ipa to ko ti gbogbo ẹ fi ṣee ṣe
Ninu ọrọ Sẹnetọ Yayi, o dupẹ lọwọ gbogbo wọn ipade to waye naa ati atilẹyin nla to ri gba latọdọ awọn agba ẹgbẹ.
O waa ṣeleri pe oun ko nii foju bintin wo ipade ti wọn ṣe naa,ipade isọkan ti ko lẹgbẹ lo pe e.
Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Gomina Dapọ Abiọdun, Sẹnetọ Gbenga Daniel ati Sẹnetọ Ibikunle Amosun fawọn ipa ti wọn ko ti wọn fi ṣe aṣeyọri .
Adeọla waa bẹbẹ fun isọkan laarin ara wọn, o ni lati akooko yii lọ awọn ti di ẹbi kan naa.
No comments:
Post a Comment