Ẹgbẹ to n ṣapero ọrọ aje nilẹ Ẹgba ṣepade afojusun bi idagbasoke yoo deba ilẹ naa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 19 April 2026

Ẹgbẹ to n ṣapero ọrọ aje nilẹ Ẹgba ṣepade afojusun bi idagbasoke yoo deba ilẹ naa


Ẹgbẹ to n ṣe apero ọrọ aje nilẹ Ẹgba, ti fimọ sọkan pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lati wa gbogbo ọna ti idagbasoke yoo fi tubọ tẹsiwaju nipa ọrọ ajẹ kaakiri ilẹ naa.

Eyi ni abajade ipade ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta,Satide, to kọja yii nibi ti wọn ti jọ forikori lati wa ọna ti igbega yoo fi tubọ ba ọrọ aje nilẹ Ẹgba atawọn to n gbe nibẹ.

Ninu ọrọ Dokita Gbenga Adeoye to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa lakooko to n ki wọn kaabọ sibi ipade ọhun lo ti kọkọ dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ yii fun ifarajin wọn lati le jẹ ki idagbasoke deba ilẹ Ẹgba.

Bakan naa lo fi akoko ọhun ki Dokita Lanre Biobaku to ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn, o waa gba a lamọran lati lo ọgbọn, imọ ati oye ti Ọlọrun fi fun nipa ẹkọ, lati fi ṣatilẹyin fun ẹgbẹ naa.

O ṣọ pe ipa pataki ni ikansiraẹni n ko lawujọ, to si n mu idagbasoke ba awujọ.

Dokita tun ṣalaye siwaju pe o ṣe pataki lati maa kan si gbogbo awọn ọmọ ilẹ Ẹgba ti wọn di ipo pataki mu lawujọ, yala nipinlẹ ati ijọba apapọ,lati maa gba wọn niyanju lati lo awọn ipo ti wọn wa fun itẹsiwaju ilẹ Ẹgba.

Lara awọn nnkan ti wọn tun mẹnuba  nibi ipade wọn ọhun ni bo ṣe ṣe pataki lati maa sọ bi eto iṣuna ọdun 2026, nilẹ Ẹgba ati ipa to n ko.

Bẹẹ ni wọn tun mẹnuba ọna ti wọn le gba lati maa ṣatilẹyin fun ayẹyẹ ọdun Liṣabi lọna ti yoo tun mu anfaani nla ba ọrọ aje.

Ẹgbẹ to n ṣapero ọrọ aje ilẹ Ẹgba tun gboriyin bi wọn ṣe mu igbega ba aṣọ kampala ati adirẹ, eyi ti wọn mọ mọwọn nilẹ Ẹgba, wọn wa n fẹẹ kawọn eeyan tẹsiwaju lori ẹ, nipa mimu lakooko inawo gẹgẹ bii aṣọ ẹbi.

Bẹẹ ni wọn rọ awọn ọmọ Ẹgba ti wọn wa nipo yala nipinlẹ tabi apapọ lati ni ipa pataki ti wọn yoo ma ko fun idagbasoke agbegbe wọn.

Bakan naa, Abiọdun Karounwi tun gba wọn niyanju lati ṣatilẹyin fun ileewe giga yunifasiti ijọba apapọ ẹkọṣẹ ogun ati ilera ni gbogbo ọna to ba yẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages