Tunde Lẹmọ ki Yẹmi Sanusi ku oriire gẹgẹ bi alaga fẹgbẹ oṣelu APC Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 3 March 2026

Tunde Lẹmọ ki Yẹmi Sanusi ku oriire gẹgẹ bi alaga fẹgbẹ oṣelu APC Ogun



Oludije gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Oloye Tunde Lẹmọ ti ṣapejuwe ipade gbogbogboo ẹgbẹ ọhun to waye niluu Abẹokuta, gẹgẹ bi eyi to dara ju, to si mu isọkan dani.

O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade ọhun, o ni inu oun dun bi gbogbo ẹ ṣe lọ nirọwọ rọsẹ,ti ko muu wahala kankan dani.

 Bakan naa lo lo anfaani naa lati ki Oloye Yẹmi Ṣanusi ku oriire gẹgẹ bi wọn ṣe daa pada sipo alaga ẹgbẹ naa.

Oloye Tunde Lẹmọ waa gboriyin fawọn ti wọn ṣeto ipade gbogbogboo ọhun ti wọn fi yan awọn oloye tuntun ti wọn yoo tukọ ẹgbẹ fọdun mẹrin.

Bẹẹ lo tun sọ pe idunnu nla lo jẹ pe awọn alajọ eto idibo naa wa nijoko ipade ti yoo gbe wọn wọnu ibo fọdun 2027, labẹ adari wọn, Aarẹ Bọla Tinubu.

Tunde Lẹmọ tun waa tẹnumọ pe ki i ṣe ahesọ pe oun jade dupo gomina, o ni ko sewu, nitori oun mọ pe oun koju oṣuwọn lati di gomina lọdun 2027.

O waa gba awọn ọmọ ẹgbẹ APC nimọran lati wa ni isọkan, ki wọn si yẹra fun ẹtanu oṣelu.

No comments:

Post a Comment

Pages