APC ipinlẹ Ogun tun yan Yẹmi Sanusi si ipo alaga ẹgbẹ wọn. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 3 March 2026

APC ipinlẹ Ogun tun yan Yẹmi Sanusi si ipo alaga ẹgbẹ wọn.

Inu gbọngan aṣa ibilẹ to wa niluu Abẹokuta kun fọfọ fun ipade gbogbogboo ẹgbẹ oṣelu APC, tipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti wọn tun ti pada yan Oloye Yẹmi Ssnusi gẹgẹ bi alaga wọn.

Nibi ipade ọhun ni Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, igbakeji ẹ, meji ninu awọn sẹnetọ, awọn aṣoju ṣofin atawọn agba ẹgbẹ naa ti peju pesẹ.

Bẹẹ ni ajọ eleto idibo iyẹn INEC, naa wa nibẹ lati dari ipade gbogbogbo ọhun. Bakan naa ni wọn yan awọn mọkandinlogoji sawọn ipo ninu ẹgbẹ naa, lara wọn ni Ọgbeni Olufẹmi Nuberu, to dipo alukoro ẹgbẹ naa mu.

Oloye Wale Ohu, alaga igbimọ to ṣeto ibo ipade naa ṣalaye pe ẹgbẹrun kan ati ọgọsan awọn aṣoju kaakiri ipinlẹ Ogun, lo sọ pe wọn kopa nibi eto ọhun.

Ninu ọrọ Oloye Yẹmi Sanusi, nigba to n tẹwo gba ipo ọhun lẹẹkẹta, o dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun ati Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori bi wọn ṣe mu igbooro ba ẹgbẹ naa 

O waa ṣeleri pe oun atawọn oloye ẹgbẹ yooku yoo jọ ṣiṣẹ pọ ni irẹpọ fun idagbasoke ẹgbẹ bẹẹ lawọn ko nii fi apa kan silẹ da apa kan si.

O ni ipilẹ ti ẹgbẹ naa ti wa lati ibẹrẹ lawọn yoo rii pe o tubọ tẹsiwaju si pẹlu idaniloju pe awọn ko nii jawọn ọmọ ẹgbẹ ni tan an mọ.

Nigba ti Gomina Dapọ naa sọrọ, o fi idunu ẹ han lori bi ipade naa ṣe lọ lsimu wahala kankan dani titi ti wọn fi pari ẹ.

O waa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati rii pe wọn ṣiṣẹ takuntakun fun ti ibo to n bọ lọdun 2027, lati rii pe wọn jawe olubori.

No comments:

Post a Comment

Pages