Ki obinrin to gboju gboya, ko sọ pe oun fẹẹ bawọn ọkunrin figagbaga lati dije fun ipo gomina, to si n tẹnumọ mọ ọn pe oun ko dije lasan bi ko ṣe pe oun yoo di gomina lọdun 2027, ṣe ẹ rii pe Iyabọ ọmọ aarẹ wa ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko muu ni kekere.
Ọrọ Yoruba kan sọ pe agbo to tadi mẹyin, agbara lo lọ mu wa bẹẹ lọrọ ri fun Iyabọ, nitori a ti gbọ nipa ẹ nidii oṣelu, o ti pẹ, tawọn kan tiẹ sọ pe boya o ti dagbere fun oṣelu .
Bi ẹ ba gbagbe ẹ jẹ ki n ran yin leti pe lakooko iṣakoso Ọtunba Gbenga Daniel, ni obinrin yii ti kọkọ jẹ kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun.
Lẹyin ni obinrin ti wọn tun pe ni Iyaniwura tun dipo sẹnetọ lagbegbe Ogun central, gbogbo igba yii inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa.
A fi bigba ti oṣupa ba yọ loke ni irawọ obinrin yii tun gbode nidii oṣelu, to ni dandan oun gbọdọ jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ko si nnkan ti ọkunrin ṣe, ti obinrin ko le ṣe.
O ni oun ṣetan lati sin awọn ọmọ ipinlẹ Ogun tọkantọkan bi wọn ba fun oun laaye lati gba tikẹẹti, ti oun si wọle, o ni irọrun ati idẹra lo maa ba de.
Idi niyii ti ọrọ fi kan gbogbo wa nipinlẹ Ogun, lati gbarkutu ti obinrin yii, ẹ jẹ ka fawọn obinrin laaye lati da wa.
Ẹgba, Ijẹbu ati Yewa, ẹ jẹ ka mu ẹlẹyamẹya kuro nibẹ, ki a gbaruku ti irawọ obinrin yii lati dije.
Ẹyin agba oṣelu APC,anfaani nla kan ree o, ẹ ran ti lọpọ awọn orileede lawọn obinrin ti jẹ aarẹ, ti wọn jẹ gomina, ẹ jẹ ka fun Iyabọ Ọbasanjọ laaye, Ogo ipinlẹ Ogun ni, ẹ ma jẹ ko wọmi.
No comments:
Post a Comment