Emi o ri tawọn to n fọwọ si oludije gomina kan ro, nitori emi lo kan- Gboyega Nasir Isiaka - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 22 March 2026

Emi o ri tawọn to n fọwọ si oludije gomina kan ro, nitori emi lo kan- Gboyega Nasir Isiaka

Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn /  Yewa North ti sọ pe bawọn kanselọ, ọmọ ile igbimọ aṣofin atawọn mii kan ṣe dide ti wọn sọ pe awọn fọwọ si Senẹtọ Ọlamilekan Adeọla fun ipo gomina lọdun 2027, ko tun irun kankan lara oun, nitori ohun to da oun loju ni pe oun ni ipo naa kan.

Ọkunrin yii toun naa jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to n bọ ọhun sọ pe ọpọ awọn ti wọn fa ẹnikan kalẹ yii lọrọ ara ti wọn gan an ko ti ye wọn, ti wọn ko mọ boya tikẹẹti ati dije yoo tẹ wọn lọwọ.

O sọrọ yii lakooko to n fikunlukun pẹlu awọn oniroyin kan niluu Abẹokuta, o sọ pe eyi to ṣe pataki to da oun loju ni pe oun nipo gomina Ogun ọdun 2027 kan, to si da oun loju pe didun ni ọsan yoo so.

Gboyega tọpọ awọn eeyan tunmọ si GNI, ṣalaye pe tẹlẹtẹlẹ loun sọ nigba kan ri oun ko tii le sọ nigba erongba oun fọdun 2027l, ṣugbọn bayii, oun ti ṣetan lati sọ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun pe oun yoo jade dupo gomina.

O ni ki i ṣe pe oun wa kede nigba ti akoko ba to oun yoo jade sita gbangba lati kede erongba oun gẹgẹ bi oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun.

O sọ pe igba kẹrin ree toun yoo gbe igbesẹ lati jade dupo ọhun.O waa sọ pẹlu igboya pe awọn iriri toun ti ni yoo tun ran oun lọwọ pẹlu.

Oludije gomina ọhun tun tẹsiwaju pe gbogbo nnkan ti eeyan ni lati fi kun oju oṣuwọn fun ipo ọhun ni Ọlọrun ọba jogun foun.

GNI tun tẹsiwaju pe" Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe mo fẹẹ dije dupo gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2027, nigba ti ma ba kede sita gbangba gbogbo yin naa ni ẹ ma wa nibẹ"

Bẹẹ lo tun sọ pe ko si ahesọ ọrọ lasan lawọn kan gbe sita pe Gomina Dapọ Abiọdun lo ṣonigbọwọ foun lati dupo naa, o ni irọ to jinna soootọ ni.

O fikun ọrọ ẹ pe lati bi ọsẹ mẹta loun ti ṣepade pọ pẹlu ẹlẹgbẹjẹgbẹ lati jẹ ki wọn mọ pe mo fẹẹ jade dupo.

O tun sọ pe " Gbogbo nnkan ti mo fi le koju oṣuwọn ni mo ni, ojulowo ọmọ ipinlẹ Ogun ni mi, ko si nnkankan ti wọn le fi pamọ nitori mi, mo waa rọ gbogbo awọn ti yoo ṣeto ibo naa lati fi oootọ inu ṣe.


No comments:

Post a Comment

Pages