Ibo Gomina:Awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ni Ọbafẹmi Owode ṣe ipade pẹlu Iyabọ Ọbasanjọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 23 March 2026

Ibo Gomina:Awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ni Ọbafẹmi Owode ṣe ipade pẹlu Iyabọ Ọbasanjọ

Lati le jẹ kawọn araalu mọ pe ko mu erongba lati dije fun ipo gomina lọdun 2027 ni kekere, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ tun ti ṣepade pọ pẹlu awọn agba ẹgbẹ oṣelu APC to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode,nipinlẹ Ogun.

Ipade ọhun to waye ni Onimọ ẹrọ Akeem Babatunde Adeṣina ti ṣaaju awọn yooku ẹ ki Iyabọ kaabọ si aarin wọn.

Ninu ọrọ awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ti wọn nikọọkan ni wọn ti gboriyin fun Ọjọgbọn Iyabọ Ọbasanjọ, lori bo ṣe sabẹwo waa si ọdọ wọn ati pe oun lẹni akọkọ ti yoo ṣe bẹẹ ninu awọn oludije wọn.

Bẹẹ ni wọn mẹnuba awọn ipa ti obinrin naa ti ko sẹyin lakooko to da ẹgbẹ ajọ Iyaniwura silẹ, eyi ti wọn lo ti tun ọpọ aye awọn eeyan ṣe.

Wọn ni iru aṣaaju rere tawọn eeyan  n fẹẹ lakooko yii ni obinrin naa ti yoo bu omi rin gbogbo ilakọja awọn araalu.

Awọn agba ẹgbẹ nijọba ibilẹ naa waa gba lamọran lati ma ṣe rẹwẹsi ọkan ninu ipinnu ẹ lati dije fun ipo ọhun pẹlu adura pe Ọlọrun- yoo mu ileri ẹ ṣẹ.

Ninu ọrọ Sẹnetọ Ọbasanjọ lo ti kọkọ fi ẹmi imoore han lori bi wọn ṣe gba tọwọ tẹsẹ. O sọ pe oun wa lati waa fi ọla ati ọwọ toun ni fawọn agba ẹgbẹ han.

O ni oun ṣetan lati ṣlṣẹ pọ pẹlu wọn lati le mu ipinlẹ yin dun un wo loju lọjọ iwaju. Bẹẹ lo ṣeleri fun wọn pe oun yoo da ifikunkukun ati ipade loorekoore pada gẹgẹ bi oloṣelu to ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ara igberiko.


1 comment:

Pages