Obinrin naa sọrọ lakooko to n kopa lori eto nileeṣẹ redio Paramount to wa niluu Abẹokuta lonii, o sọ pe nnkan to wa niwaju oun ni bi oun yoo ṣe sin ipinlẹ Ogun pẹlu awọn ipinnu ati eto ni fun wọn.
O sọ pe imurasilẹ oun kọja tawọn to n dlije alaṣọ alarabara, ati pe oun kan jade lati jẹ kawọn eeyan ri oun bi ko ṣe pe ipo gomina to n bọ naa, ọwọ oun lo bọ si.
Senetọ to tun gboye imọ ijinle ọjọgbọn tun ṣalaye siwaju pe jijade oun nii ṣe pẹlu awọn iriri ati ipa to ti ko sẹyin, eyi to ni yoo tubọ wulo foun to ba depo gomina.
O waa fikun ọrọ ẹ pe lati dije fun ipo gomina ki i ṣe nnkan to rọrun rara, o waa fẹni to ṣetan lati sin araalu tọkantọkan ki i ṣe fawọn isansa.
Iyabọ Ọbasanjọ tun mẹnuba ipo ti eto ẹkọ ati ipa tawọn olukọni n ko, eyi to sọ pe o yẹ ki idanilẹkọọ maa wa loorekoore ni eyi ti yoo mu idagbasoke ba awujọ.
O waa rọ ijọba atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lati tunbọ da si eto ẹkọ,atawọn bii ilera ati ọgbin lọna ti yoo mu igbe aye idẹrun ba araalu.
No comments:
Post a Comment