GNI pin ounjẹ fawọn alaawẹ ni wọn ba n fadura ranṣẹ si - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 11 March 2026

GNI pin ounjẹ fawọn alaawẹ ni wọn ba n fadura ranṣẹ si


Titi di akoko ta a wa yii lawọn araalu fi adura ranṣẹ si Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka ti wọn tun pe ni GNI, to n ṣoju agbegbe Imẹkọ- Afọn/ Ẹgbado North, nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja,lori bo ṣe pin ẹbun ounjẹ fawọn alaawẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igba akọkọ kọ ree, ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ APC  maa n ṣe nnkan bayii eyi ti wọn pe ni 'Ramadan Package'

Bo tilẹ jẹ pe ti akoko yii yatọ nitori bawọn musulumi ṣe n gbawẹ bẹẹ lawọn onigbagbọ ta a mọ si Krisitẹẹni naa n gba.

Idi niyii ti wọn fi pn awọn ẹbun ounjẹ naa kaakiri awọn ijọba ibilẹ ati wọọdu kọọkan to wa nipinlẹ Ogun.

Ko si sẹni to ri awọn ẹbun ounjẹ naa ti ko ni ṣadura fẹni to ṣagbekalẹ ẹ, nitori awọn nnkan ti wọn ko sibẹ fawọn eeyan lati fi ṣara rindin.

Ọpọ awọn eeyan to jẹ anfaani ẹbun ounjẹ ninu Ramadan yii ni wọn fi idunnu wọn,ti wọn si ṣadura fun Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, ti wọn ṣi n fadura ranṣẹ sii.

Ọkan lara wọn lati Abẹokuta South, Iyaafin Mọdina Salawu, dupẹ lọwọ GNI fun iranlọwọ ounjẹ ti wọn ri gba lati ọdọ ẹ. Obimrin ọhun waa gbadura pe niwoyi ọdun to n bọ ipo Gomina to n lepa, irọrun ni Ọlọrun yoo fi fun un.

Bakan lọrọ ri fawọn yooku ti wọn jẹ anfaani, ti wọn si fi ẹmi imoore wọn han s GNI.  

No comments:

Post a Comment

Pages