O sọrọ yii nibi idanilẹkọọ asiko awẹ, ẹlẹẹkẹta iru ẹ, to waye niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun, nibi tawọn ẹlẹsin musulumi atawọn ọmọ lẹyin Yayi ti peju pesẹ.
O sọ pe ipinlẹ Ogun jẹ eyi to ni isọkan ti alaafia si jọba laisi ẹlẹsin kan yatọ, o ni ko wa yẹ ki wọn waa fẹẹ fi akoko yii da nnkan ru nipa ẹsin lati yan olori.
Sẹnetọ Adeọla tun fikun ọrọ ẹ ninu eto ọhun ti wọn fi sọri Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu pe idi pataki tawọn fi gbeto naa kalẹ lakooko awẹ Ramadan ni lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun bẹẹ ni ki wọn tun lo lati fi ṣadura.
O rọ awọn eeyan lati fi duro ninu igbagbọ wọn ki wọn ma si ṣe gba kawọn oloṣelu kan fọrọ ẹsin mu wọn mọle nitori iwa imọtara ẹni ti wọn fẹẹ ṣe.
Yayi tun sọ pe pẹlu boun ṣe jẹ onigbagbọ, o ti le ni ẹgbẹrun kan musulumi toun ti ṣatilẹyin fun un lati ran an lọ si mẹka.
O waa rọ wọn lati yan gomina rere, ti yoo mu wọn de ilẹ ileri, bakan naa lo tun gbori fun Aarẹ Tinubu fawọn ipa to ti ko lori ọrọ aje ilẹ wa.
Ninu iwaasu Sheik Jamiu Sanusi nibi idanilẹkọọ naa lo ti gboriyin fun Sẹnetọ Yayi fawọn ipa ribiribi to ti ko bẹẹ lo rọọ lati ma ṣe wẹyin.
No comments:
Post a Comment