Eto ọhun to waye ni ọfiisi ẹgbẹ ọhun to wa ni Ijẹja, niluu Abẹokuta, l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ naa, Abayọmi Sanyaolu, o sọ pe akoko tawọn ṣe adura ọhun dara pupọ, nitori bi wọn ṣe n murasilẹ fun ibo to n bọ lọdun to n bọ.
O sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati beere fun itọsọna Olọrun lori gbogbo awọn oludije atawọn ajọ eleto idibo fun idari lati ọrun wa.
O fikun ọrọ ẹ pe pataki ni adura, ifẹ ati iṣọkan n ko ninu aye awọn eeyan paapaa julọ laarin awọn oloṣelu.
Abayọmi to tun jẹ alaga fẹgbẹ IPAC nipinlẹ Ogun tun tẹsiwaju pe agbara to wɛ ninu adura ko kere ati pe lẹyin tawọn ba ṣakojọ awọn eeyan, adura lo kan lati fi tii lẹyin.
O waa rọ awọn ẹgbẹ APM lati wa nisọkan, ki ifẹ si jọba laarin wọn. Bẹẹ lo tun ni ki wọn ko ara wọn nijanu, ki wọn si wa tọkantọkan pẹlu ẹgbẹ.
Lori fifi ẹgbẹ silẹ,alaga ẹgbẹ naa ni awọn ko ni ikunsinu kankan si ẹni to ba wu lati gbe igbesẹ naa.
Bẹẹ lo pe irufẹ awọn eeyan yii lati pada sinu ẹgbẹ ki wọn si dipo wọn mu pẹlu ileri pe wọn ko nii kabamọ.
Gbogbo awọn ti wọn sọrọ lọjọ naa ni wọn gba pe igbesẹ adura ti wọn gba naa ni kọkọrọ oriire fun itẹsiwaju wọn ninu oṣelu.
No comments:
Post a Comment