Ẹ jẹ ka fi ayẹyẹ ọdun Liṣabi wa iṣọkan ati idagbasoke oṣelu fun ilẹ Ẹgba- Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 27 March 2026

Ẹ jẹ ka fi ayẹyẹ ọdun Liṣabi wa iṣọkan ati idagbasoke oṣelu fun ilẹ Ẹgba- Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi


Pẹlu bi ayẹyẹ ọdun Liṣabi ṣe n lọ lọwọ ti aṣekagba ẹ yoo waye ni ọla,Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, to tun jẹ Ọdọfin Kemta ni Ẹgba, ti rọ awọn ọmọ Ẹgba lati lo ayẹyẹ ọhun ṣatunṣe oṣelu ti yoo mu isọkan ati idagbasoke ba ipinlẹ Ogun.

Ninu atẹjade ti ojulowo ọmọ Ẹgba naa fi sita, lo rọ wọn lati lọ ọdun Liṣabi Agbongbo Akala, lati fi ṣapọnle ẹ.

O ṣalaye pe akoko ti to fawọn ọmọ Ẹgba lati mọ ibi ti wọn wa ninu oṣelu, ki wọn si fi erongba wọn han fun ipo gomina lọdun 2027.

Oludasilẹ ẹgbẹ to n wa ọna abayọ iyẹn The Alternative sọ pe ki wọn ma ṣe gbagbe bi wọn ṣen ṣe tẹlẹ, ki wọn ma jẹ ko parun iyẹn Ẹgba, Ijẹbu-Rẹmọ ati Yewa/Awori, o waa ṣekilọ pe gbogbo nnkan to le ba eto ati ilana yii jẹ le ba nnkan jẹ pupọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo erongba ti wọn ro lati tẹsiwaju agbara ipo gomina lati ipẹru jẹ ọkan lara ewu to le wa fun ayipada itan  ipinlẹ Ogun.

Bẹẹ lo pariwo lori ihuwasi awọn ọba alade ti wọn ki bọ idagbasoke oṣelu lori bi Ọba Kehinde Olugbenle ṣe fẹẹ fi oṣelu pa ẹnu awọn Ẹgba mọ.

O waa ṣe ikilọ pe bi nnkan ṣe n lọ, bi wọn ko ba ṣatunṣe ipo keji si ikẹta ni Ẹgba yoo ba ara wọn ninu ipo agbara ipinlẹ Ogun.

Ṣowunmi wa mẹnuba awọn ifasẹyin idagbasoke ti oṣelu ti mu bawọn agbegbe to so Ẹgba yipo bii Abẹokuta South, Abẹokuta North, Ọdẹda, Ọbafẹmi Owode,Ifọ ati Ewekoro.

O ṣalaye pe bi wọn ṣe da awọn ohun iṣẹ akanṣe imayedẹrun duro lawọn bii Ewekoro ati Abẹokuta jẹ awọn ẹri aridaju pataki.

Bẹẹ lo tun sọ nipa ọrọ aje ati idagbasoke eto ẹkọ, Ọdọfin Kemta ilẹ Ẹgba pe ipe fun idasilẹ okoowo nla lawọn ileewe giga yunifasiti bii eyi ti wọn ti n kọ nipa ogun,o ni ilẹ Ẹgba n fẹ idagbasoke nla pẹlu ipo ti wọn wa atawọn ipa ti wọn ti ko.

O ni kawọn agba ilẹ Ẹgba tun ro ipo ti Aaréẹ orileede yii, Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bi Aarẹ Ago ilẹ Ẹgba lati fi sunmọ ọn.
 
O ni ifikunkukun pẹlu awọn Ẹgba ṣe pataki, oun ni yoo si sọ ọjọ iwaju oṣelu nipinlẹ Ogun.


No comments:

Post a Comment

Pages