Laaarọ niwe iroyin oloyinbo kan gbe jade pe o ṣe e ṣe ki ẹgbẹ oṣelu APC fawọn kan ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina ninu ibo ọdun to n bọ.
Awọn tiwe iroyin ọhun tọka si ni Ọbafẹmi Hamzat, igbakeji Gomina nipinlẹ Eko, Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla tọpọ mọ si Yayi ati Sharadeen Alli, ti wọn wa lati ipinle Eko, Ogun ati Ọyọ.
Ibi ipade kan ti wọn lawọn Gomina kan ṣe pẹlu Aarẹ Bọla Ahmed atawọn kan ni wọn ti sọ pe iroyin ọhun ti jẹ jade.
Koda wọn sọ pe awọn to ti jẹ gomina tẹlẹ ni wọn yoo fa gomina kalẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ ọhun.
Idi niyii ti wọn fi sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ awọn ti wọn darukọ naa ni wọn yoo fun ni tikẹẹti ṣugbọn ti ko ti ṣi idaniloju pe wọn yoo fun wọn.
Afi bawọn alatilẹyin Yayi ṣe fẹẹ sọ o ṣe e ṣe di ootọ ti wọn si ti n ki ara wọn ku oriire.Boya ka sọ pe ara ọgbọn ẹtan oṣelu ni wọn n da lati tun fi oludije wọn pariwo.
Amọ sa, ohun to daju ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ko tii kede lawọn ipinlẹ Yoruba mẹta ti ibo gomina yoo ti waye lọdun to n bọ.
Gbogbo eyi tawọn kan ki ara wọn ku oriire, wọn kan mu inu ara wọn dun, bi akoko ba to araalu funra wọn yoo ri.
No comments:
Post a Comment