Awọn agba oṣelu ijọba ibilẹ Ifọ gboṣuba fun Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 24 March 2026

Awọn agba oṣelu ijọba ibilẹ Ifọ gboṣuba fun Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ

Tilu-tifọn lawọn agba ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Ifọ fi waa pade Sẹnetọ Iyabọ Oluṣọla Ọbasanjọ, lana an, lakooko to ṣabẹwo lọ sọdọ wọn lati fi erongba ẹ han fun idije Gomina ninu ibo to n bọ.

Nibi ipade to ṣe pẹlu awọn agba ẹgbẹ ọhun ni aṣaaju wọn, Oloye Jọju Fadairo, ti ki i Iyabọ Ọbasanjọ kaabọ si aarin wọn ati pe ile ile lo wa, ọmọ onilẹ ni.

O ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi akọni ẹlẹyinju aanu tọpọ awọn araalu ti ti ara ẹ dide paapaa julọ, nipaṣẹ ajọ Iyaniwura to daa silẹ, tawọn eeyan si  n jẹ anfaani ẹ titi di akoko yii.

O lawọn nigbagbọ ninu ẹ pe adari rere ni yoo jẹ lati gbe ipinlẹ Ogun dide si ju bo ṣe waa lọ.

Ninu ọrọ Iyabọ Ọbasanjọ,o dupẹ  lọwọ wọn fun bi wọn ṣe gba oun lalejo ati pe oun wa lati fi ọla fun wọn,ati lati tun jọ jiroro nipa igbega ipinlẹ Ogun.

O waa ṣeleri pe lati jọ ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agba ẹgbẹ oṣelu nijọba ibilẹ naa. Lara awọn to tun wa nibẹ ni Ọnarebu Taiwo Oluọmọ, Ọnarebu Sikirulai Ogundele,Oloye Oluwọle Ẹnilọlobọ atawọn mii in.

No comments:

Post a Comment

Pages