Awọn obinrin fariga, wọn ni asiko awọn lati ṣe Gomina ree, ki wọn fun Iyabọ Ọbasanjọ laaye nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 31 March 2026

Awọn obinrin fariga, wọn ni asiko awọn lati ṣe Gomina ree, ki wọn fun Iyabọ Ọbasanjọ laaye nipinlẹ Ogun

O fẹẹ jẹ pe ọrọ ibo Gomina fọdun 2027  nipinlẹ Ogun ti n gbọna mii yọ bayii nitori bawọn obinrin kan ṣe fariga pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ṣatilẹyin fun obinrin akẹgbẹ wọn to jade dupo ọhun iyẹn Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ.

Ki i ṣe tuntun mọ pe obinrin naa ti jade bọ sita pe ko si nnkan buruju ti obinrin ba jade sita lati figagbaga pẹlu awọn ọkunrin, nitori ko si nnkan ti wọn n ṣe tawọn naa ko le ṣe.

Idi niyii to fi sọ pe ibo Gomina to n bọ yii, oun ti gbaradi lati dupo ọhun lọdun 2027,ere lawọn kan kọkọ n pe amọ nibi to le de bayii oludije naa ti sọ pe oun duro gẹgẹ bi akọni, ko si nnkan to le yẹ ipinnu oun.

Ọpọ awọn ti wọn ti gbọ nipa erongba Iyabọ Ọbasanjọ tawọn kan tun pe ni Iyaniwura ni wọn gba tọkantọkan ni o fi jade to si ni igboya to daju pẹlu.

Koda nibi to ti ba iṣẹ ẹ de ọpọ awọn ti wọn jọ jẹ oludije gomina ni ko tii ṣe ilata ẹ, ẹnu lasan ni wọn fi n pariwo pe awọn fẹẹ jade.

Bakan lo ṣe jẹ pe ṣe lawọn obinrin kan dide lakooko ti wọn sọ pe akoko tawọn ni eleyii, nnkan ti ọkunrin ṣe, obinrin le ṣe ju bẹẹ lọ.

Iru apẹẹrẹ bẹẹ ni ti ọdun Liṣabi to waye laipẹ yii niluu Abẹokuta pẹlu pe Sẹnetọ Ọbasanjọ ko si nibẹ, to wa niluu Abuja,nibi ipade ẹgbẹ oṣelu APC, sibẹ ara kekere kọ ni awọn alatilẹyin ẹ, paapaa julọ awọn obinrin da lọjọ naa.

Iyẹn nikan kọ, kaakiri awọn wọọdu lawọn ijọba ibilẹ lawọn obinrin kan ti n ba iṣẹ lọ, ti wọn si sọ pe Iyabọ Ọbasanjọ  ni o.

Ọkan lara awọn obinrin nijọba ibilẹ Abẹokuta South, Arabinrin Fọlaṣade Idowu sọ pe iwuri nla lo jẹ pe obinrin bi ti wọn jade dupo gomina,pe ara idagbasoke tawọn fẹẹ ninu oṣelu ni.

Obinrin naa sọ pe lawọn orileede kan nilẹ Afrika ati lagbaaye, awọn obinrin ti n di aarẹ orileede koda gomina lawọn ipinlẹ wọn, o ni ko si nnkan to buru ju to ba bẹrẹ ni orileede wa Naijiria .

Lọrọ kan adura lawọn obinrin oloṣelu  n gba pe ki ipo naa ma bọ mọ wọn lọwọ, gbogbo nnkan to wa ni ikapa wọn lawọn yoo lo.

No comments:

Post a Comment

Pages