Abayọmi Sanyaolu di alaga fẹgbẹ apapọ oṣelu IPAC lẹẹkẹji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 31 March 2026

Abayọmi Sanyaolu di alaga fẹgbẹ apapọ oṣelu IPAC lẹẹkẹji

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni ẹgbẹ apapọ  oṣelu iyẹn IPAC tipinlẹ Ogun, dibo yan Kọmureedi Abayọmi Sanyaolu, gẹgẹ bi alaga wọn lẹẹkeji.

Nibi idibo to waye ọhun lawọn ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun ti kopa, eyi to waye ni ọgba ajọ eleto idibo INEC, Magbọn niluu Abẹokuta.

Iwadii fi ye wa pe alaga apapọ fẹgbẹ naa lati ilu Abuja, Dokita Yusuf Dantalle lo ṣaaju awọn eeyan rẹ yooku lati wo bi idibo ọhun ṣe lọ.

ibo mejila ni Abayọmi Sanyaolu to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu APM ni nigba ti Kọmureedi Ọkẹ, toun jẹ alaga Accord, ti wọn jọ dupo ni ami ayo marun un.

Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn ṣebura fun Abayọmi dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ fun igbagbọ ti wọn ninu ẹ ti wọn fi dibo yan an lẹẹkeji pẹlu ileri pe oun ko nii doju ti wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages