Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, irẹsi ni wọn sọ pe awọn onifayawọ ọhun fi ọkadako wolu tawọn ẹṣọ aṣobode yii fi pade wọn ti wọn si gba gbogbo apo irẹsi naa.
Ninu atẹjade ti Zakari Chado to jẹ agbẹnusọ fawọn aṣọbode nipinlẹ Ogun, fi sita, lo ti ṣalaye pe lẹyin ti wọn gba irẹsi ọhun tan lawọn fayawọ yii lọọ ko ara wọn jọ pẹlu ibọn ti wọn si doju ogun kọ awọn kọsitọọmu naa.
Fun bi ọgbọn iṣẹju ni wọn sọ pe iro ibọn fi n dun lakọlakọ laarin awọn mejeeji, ti ọta ibọn si mu ọkan lara fayawọ naa mọlẹ.
Nibi ti wọn si ti n gbe lọ fun itọju lo ti ku.A gbọ pe wọn ti mu ẹni to ran wọn niṣẹ lati ko irẹsi naa wọlu, to si ti wa ni akolo awọn ẹṣọ aṣọbode yii.
Ọga agba ẹṣọ oju ọna nipinlẹ Ogun, Olukayọde Afẹni ti ṣapejuwe iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi eyi to buru ju ati bawọn onifayawọ ṣe doju ogun kọ awọn ọṣiṣẹ ẹ lakooko ti wọn ṣiṣẹ wọn.
O waa ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ si iṣẹlẹ yii lọwọ yoo tẹ tawọn yoo si fi jofin laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment