Adura awọn obi mi lo gba lori mi- Akẹkọọ to ṣe daadaa julọ ni FUNAAB - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 1 February 2026

Adura awọn obi mi lo gba lori mi- Akẹkọọ to ṣe daadaa julọ ni FUNAAB

Joy Osiano, akẹkọọ-binrin to ṣe daadaa julọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade nileewe imọ ọgbin FUNAAB, fun ti ọdun 2025, ti sọ pe adura awọn obi oun ati ifarajin toun ni lo jẹ ki oun ṣe aṣeyọri ọhun.

Lakooko to n sọrọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹẹkẹtalelọgbọn ọhun lo ti sọ pe awẹ ati adura tawọn ẹgbẹ ọhun gba le oun lori ati atilẹyin ti gbogbo ẹbi oun ṣe tun kun pẹlu.

Omidan Joy tun ṣalaye pe ifarajin toun ti ni latigba toun ti bẹrẹ tun ran oun lọwọ, nitori oun ko figba kankan rẹwẹsi rara.

O waa lo akoko ọhun lati fi dupẹ lọwọ awọn olukọ ẹ to fi mọ awọn to n ṣe amojuto nipa ẹkọ, fawọn ipa ti ko ṣe e gbagbe ti wọn ti ko ninu aye oun.

O waa pari idupẹ si ọdọ awọn alaṣẹ ileewe naa ati Ọlọrun to fun un ni oore ọfẹ lati ṣe daadaa julọ ninu ẹkọ ẹ.

Bẹẹ lo sọ pe manigbagbe lọdun 2020 jẹ iyẹn lakooko korona fawọn ipenija to ni nigba ọhun amọ to ti waa di ayọ nla fun un.

No comments:

Post a Comment

Pages